Ìpínlẹ̀ Òndó lagogo ìkìlọ̀ fáwọn tó ńforúkọ olùdánwò sílẹ̀ lọ́nà àitọ́

Ilé ẹjọ́ fa ẹjọ́ Olúbàdàn àti Gómìnà lé adájọ́ mi lọ́wọ́
February 16, 2018
Professor Akinwumi Isola Dies at 79
February 17, 2018
Ìpínlẹ̀ Òndó lagogo ìkìlọ̀ fáwọn tó ńforúkọ olùdánwò sílẹ̀ lọ́nà àitọ́

Ìjọba ìpínlẹ̀ Òndó ti sèlérí láti fófinde èyíkèyí ilé-ìwé Girama tó bá n forúkọ akékọ sílẹ̀ fétò ìdánwò oníwe mkwa tí yóò wáyé lọ́dún yíì lọ́nà àitọ́.

Alákoso fọ́rọ̀ ètò ẹ̀kọ́ nípínlẹ̀ náà, Ojisẹọlọrun Fẹmi Agagu ló fìdí èyí múlẹ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ ètò ika ilé-ìwé tọdún 2018 tó wáyé nílu Àkúrẹ́.

Olusọaguntan Agagu sọ pé, ìjọba ìpínlẹ̀ náà tí satán láti tẹ̀lé àsẹ ìjọba àpapọ̀ fi gbógunti àwọn ìwà ìbájẹ́ kan nípasẹ̀ akesilẹ síse látoríẹ̀rọ ayélujára.

Ó wá sàlàyé pé, àkókò titó báyii fáwọn tọ́rakàn láti fọwọ́sowọ́pò pẹ̀lú ìjọba láti mágbega bá ètò ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ àyẹ̀wò fínfín síse akẹ́kọ tó bá jóko serúfẹ́ ìdánwò.

Kò sài fikun pé, gbogbo àwọn àkọsílẹ̀ tí wọ́n bá se látorí ẹ̀rọ ayèlujára lẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ niwọ́n yóò fi sọwọ́ sílesẹ́ tó ńrísétò ẹ̀kọ́ nílẹ̀ yíì, fáyẹ̀wò tó lóórin.

Ogunkọla/Animasaun

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *