Ìjọba Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti setán láti sàmúlò Ìmọ̀ ẹ̀rọ

Ife ẹ̀yẹ bọọlu àgbáyé bẹ̀rẹ̀ ní Russia
June 14, 2018
Governor Abiola Sends Eid-el-Fitri Message
June 14, 2018
Ìjọba Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti setán láti sàmúlò Ìmọ̀ ẹ̀rọ

Ìjọba Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti setán láti sàmúlò Ìmọ̀ ẹ̀rọ ìbárẹ́ẹnisọ̀rọ̀ ayé òde òní, fi sàmúgbòòrò ètò ìpalẹ̀ ẹ̀gbin àti ìdọ̀tí mọ́, àtàwọn ìpàníjà min-in tó n kojú ọ̀rọ̀ ìmọ̀tótó àyíká.

Olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà fọ́rọ̀ ètò ẹ̀kọ́, ọ̀mọ̀wé Bisi Akin Alabi ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ níbi àpérò àwọn oníròyìn tó wáyé nílu Ìbàdàn.

Ó sàlàyé pé, nípasẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ kan tí jọba Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ gbékalẹ̀, tíwọ́n pè ní ọ̀yọ́-mèsì gbé ètò àríyànjiyàn kalẹ̀ nípa ìmọ̀ ẹ̀rọ ìbáráẹnisọ̀rọ̀ ayé òde òní, níbi táwọn olùkópa yóò ti wá ojútu sọ́rọ̀ ìpalẹ̀ ẹ̀gbin mọ́, tófimọ́ sìsàwárí àwọn ibùdó ìdalẹ̀nùsí.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ, olùdarí àgbà ilé-isẹ́ aládàni kan tó ń sàmójútó  ẹ̀gbin, ọ̀gbẹ́ni Pall O’callaghan sọ́ọ́di mímọ̀ pé, ó lé láwọn olùkópa bi àadọ́ta lérúgba tó tá gba láti kópa níbi ètò àríyànjiyàn ọ̀hún.

Kẹmi Ogunkọla/wojuade

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *