Imam àgbà ilẹ̀’bàdàn: gba àwọn olósèlú nímọ̀ràn

Ekiti Traditional Rulers Task INEC on Credible Poll
June 14, 2018
Ife ẹ̀yẹ bọọlu àgbáyé bẹ̀rẹ̀ ní Russia
June 14, 2018
Imam àgbà ilẹ̀’bàdàn: gba àwọn olósèlú nímọ̀ràn

Imam àgbà ilẹ̀’bàdàn, Àlhájì Abdul-ganiyu agbọ́tọmọkákeré ti gba àwọn olósèlú nímọ̀ràn láti fàayè gba àláfìa, paapa jùlọ bí ìdìbò gbogbogbò ọdún tí mbọ̀ ti n súnmọ́ etílé.

Imam àgbà ilẹ̀ ìbàdàn, Àlhájì Abdulganiyu Agbọtọmọkekere ló gba wọn nímọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lóni níbi ìrun tó wáyé láti parí ààwẹ̀ Ramadan, èyí tó wáyé ní Yídì Agodi Ìbàdàn.

Imam Agbọtọmọkekere rọ àwọn olósèlú láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn ará ìlú nípasẹ̀ àwọn èètò tí yo se àwọn èèyàn lánfaàní, kí wọ́n sì yàgò fún ìwà ipá.

Ó fi kun un pé, èrògbà láti sisẹ́ sin ìlú ló yẹ kó wà lọ́ọ́kàn àyà àwọn tó bá ńdi ipò òsèlú.

Ẹwẹ, Àlhájì Agbọtọmọkekere tẹnu mọ́ọ̀ pé, ó se pàtàkì fún gbogbo Mùsùlùmí láti fi àwọn ẹ̀kọ́ àawẹ̀ Ramadan sínu ìse tayọ àsìkò àawẹ̀ náà.

Lára àwọn èèkàn tó wà níbi Ìrun Yídì ni Olúbàdàn Ilẹ̀ẹ̀ Ìbàdàn Ọba Sọliu Adetunji àti Ikọlaba Ilẹ̀ẹ̀ Ìbàdàn tó tún jẹ́ Baba ìsàlẹ̀ Mùsùlùmí Ilẹ̀ẹ̀ Ìbàdàn Àlhájì Abdullateef Oyedele.

Àwọn tó bá oníròyìn wa sọ̀rọ̀ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Allah tó mú wọn rí òpin àawẹ̀ náà lálafaafìa.

Kẹmi Ogunkọla

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *