Àwọn elétò Àabò ńgbé ọ̀kan òjọ̀kan ìgbésẹ̀ lórí ìdìbò Gómìnà

Amosun Hails Ogun PCRC
June 27, 2018
Akeredolu Promises Timely Assistance to Fire Victims
June 27, 2018

Níwọ̀ngbà ọjọ́ diẹ tókù kétò ìdìbò sípò Gómìnà wáyé nípínlẹ̀ Èkìtì, ó ti lé lọ́gọ̀rún àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn tíwọ́n ti mú lọ́kanòjọ̀kan ibùdó tó ń bẹ yíká àwọn ìlú àtabúlé nípínlẹ̀ náà.

Alákoso fọ́rọ̀ Ọlọ́pa nípínlẹ̀ Èkìtì, ọ̀gbẹ́ni Bello Hammed àtolùdárí àjọ àbò ara-ẹni láabòlú Civil Defence, ọ̀gbẹ́ni Solomọn Iyamu niwọ́n fìdí èyí múlẹ̀ nílu Adó-Èkìtì lákókò tíwọ́n sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìgbésẹ̀ tíwọ́n ti gbé, látiridájú pé, ètò ìdìbò náà kẹ́sẹ járí.

Àwọn ọ̀gá àjọ aláábo náà sàlàyé pé, mímú táwọn máwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn ọ̀hún ló wà lára akitiyan láti fọ Ìpínlẹ̀ náà mọ́tónítóní lọ́nà àtiridájú pé, ètò ìdìbò sípò Gómìnà tí yóò wáyé lọ́jọ́ kẹrìnlá osù keje, lọ nírọwọ́rẹsẹ̀.

ọ̀gbẹ́ni Hammed sàlàyé pé, gbogbo àwọn ami dúdú kọ̀ọ̀kan tó wà láwọn ìlú àtàwọn abúlé yíká ìpínlẹ̀ náà láwọn tí sèpalẹ̀mọ́ wọn nípasẹ̀ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ gbogbo àwọn àjọ aláábo pátá, káláfìa lè lè ba jọba.

Kò sài mẹ́nuba diẹ lára àwọn àjọ alaabo ọ̀hún, nínú èyí tatirí, ilé-isẹ́ ológun, tibùdó tón rísí ìwọlé-jáde, àjọ ẹ̀sọ́ ojú pópó, FRSC, tàjọ àabò ara ẹni lààbòlú, Civil Defence, àti bẹbẹlọ, ni wọ́n díjọ fọwọ́sowọ́pọ̀ láti tọwọ́ ìwà ọ̀daràn bẹlẹ pátápátá kó tò dàkókò ètò ìdìbò sípò Gómìnà àti lẹ́yìn tó bá parí tán.

Wọ́n wá sèkìlọ̀ fáwọn àjọ alaabo tókù tí yóò kópa níbi ètò ìdìbò ọ̀hún, láti fi ìbẹ̀rù Ọlọ́run kún gbogbo ohun tí wọ́n bá ńse, kíwọ́n sì yágò kúrò nídi àwọn isẹ́ kan, èyí tó tapo sásọ àlàà wọn.

Kẹmi Ogunkọla/Dokun Ladele

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *