Ilé isẹ́ elépo rọ̀bì mú àlékún bá epo rọ̀bì tó wà nípamọ́

Ìpínlẹ̀ Òndó sàgbékalẹ̀ àkànse ìgbìmọ̀ Ìgbẹ́jọ́
July 4, 2018
Àarẹ ilẹ̀ Faranse gbàwọn ọ̀dọ́ nímọ̀ràn lórí isẹ́ ọ̀gbìn
July 4, 2018
Ilé isẹ́ elépo rọ̀bì mú àlékún bá epo rọ̀bì tó wà nípamọ́

Ilé isẹ́ elépo rọ̀bì ilẹ̀ yíì, NNPC, sọ pé, ill Nàijírìa ti lóun yóò sáfikún epo rọ̀bì tó ń gbápamọ́ pẹ̀lú billiọnu kan àgbá epo lọ́lọ́dún kó lè bá àfojúnsùn ogógì billiọnu àgbá epo rọ̀bì dun pàdé títí ọdún 2020.

Alábojútó àgbà ilé isẹ́ NNPC, ọ̀mọ̀wé Maikanti Baru ló fìdí èyí múlẹ̀ níbi àpérò kan tóníse pẹ̀lú epo rọ̀bì àtafẹ́fẹ́ gáási tó n lọ lọ́wọ́ nílu Abuja.

Ó tọ́kasi pé, lára àwọn ìpèníjà tó ńkojú ẹ̀ka epo rọ̀bì àtafẹ́fẹ́ gaasi náà ni, àisètò àbò tómúnádoko, àyíká, owó ìdókòowò, tófimọ́ bowo epo rọ̀bì se kéré jọjọ, pẹ̀lú àfikún pé, ìjọba tówà lóde báyíì ti ń sisẹ́ takuntakun láti gbógun tàwọn ìpèníjà ọ̀hún.

Bákánà , alákoso kejì fọ́rọ̀ epo bẹtirolu, ọ̀mọ̀wé, Ibe Kachikwu, sọ pé, ìjọba àpapọ̀ kòní fọwọ́ séyikéyí isẹ́ àkànse kankan tó jẹ́ mọ tépo rọ̀bì àtafẹ́fẹ́ gaasi láwọn ilésẹ́ epo bẹtirolu, àyàfi téròngbà tómúnádoko bá wenulẹ fún irúfẹ́ isẹ́ àkànse bẹ́ẹ̀.

Kẹmi Ogunkọla/Akintunde

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *