Ìjọba Ìpínlẹ̀ Ògùn ti sọpé títọwọ́bọ̀wé kan pẹ̀lú Ìjọba ilẹ̀ Faranse lórí ọ̀rọ̀ mímú àtúnse báwọn ilẹ̀ tó ti bàjẹ́ nípínlẹ̀ náà yóò mágbega bá ìgbáyégbádùn ètò ọrọ̀ ajé Ìpínlẹ̀ náà.
Gómìnà Ìpínlẹ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Ibikunle Amosun tó fìdí èyí múlẹ̀ fáwọn oníròyìn nílu Abẹokuta sọpé, èróngbà Ìjọba ilẹ̀ Faranse ni láti ran Ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́ nídi wíwójútu sọ́rọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ àyípadà ojú ọjọ́.
Kò sài fikun pé, ó lé nígba Milliọnu Dọllar isẹ́ àkànse kan tí yóò tún sètò ìrónilágbára fáwọn àgbẹ̀ kékèké àtàwọn olóókowò min-in.
Ó sàlàyé pé, ìrètíwà pé, isẹ́ àkànse náà yóò mátunse bá ọgọ́run kan saare ilẹ̀ tó ti bàjẹ́, èyí tó wà nígbó Ìmẹ̀kọ àti Àwọ̀rọ̀ nípínlẹ̀ Ògùn.
Gómìnà tọ́kasi pé, àwọn àjọ ilẹ̀ Faranse náà yóò dásí isẹ̀ àkànse náà, èyí tí yóò pèsè isẹ́ lọ́pọ̀ yanturu.
Kẹmi Ogunkọla/Fọlarin