Godswill Akpabio ti kọ̀wé fi ipò sílẹ̀

Èètò ààbò gbó-pọn síì ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀
August 7, 2018
Wọ́n ti gba àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàijírìa nímọ̀ràn láti lo ànfàní ìmọ̀ ẹ̀rọ lọ́nà tó tọ́
August 7, 2018

Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom Ṣénatọ Godswill Akpabio ti kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ bí asaaju ẹgbẹ́ òsèlú tó ní ọmọ ilé tó kéré jùlọ ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin àgbà.

Àtẹ̀jáde láti ọ̀dọ̀ olùrànlọ́wọ́ rẹ̀ fún ìkéde, ẹ́gbẹ́ni Jackson Udom sọ́di mímọ̀ pé ìwé ìfipò sílẹ̀ náà ni wọ́n kọ sí igbá kejì asájú ẹgbẹ́ òsèlú tó ní ọmọ ilé tó kéré jùlọ, Ṣénatọ Emmanuel Bwacha.

Ìròyìn ńtọka síì pé, Ṣẹnatọ Akpabio tó ńsojú Ìwọ̀ oorun Akwa Ibom ti múra tán láti rékọjá sínú ẹgbe òsèlú APC.

Ìrètí wà pé ọ̀la ni wọ́n yo ki Ṣẹnatọ Akpabio kaabọ sínú ẹgbẹ́ APC, níbi ayẹyẹ kan ní Ikot Ekpene ní Ìpínlẹ̀ Akwa Ibom.

Ayankọsọ

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *