Wọ́n ti gba àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàijírìa nímọ̀ràn láti lo ànfàní ìmọ̀ ẹ̀rọ lọ́nà tó tọ́

Godswill Akpabio ti kọ̀wé fi ipò sílẹ̀
August 7, 2018
NYSC DG Warns Corps Member against Unlawful Travel
August 7, 2018
Wọ́n ti gba àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàijírìa nímọ̀ràn láti lo ànfàní ìmọ̀ ẹ̀rọ lọ́nà tó tọ́

Wọ́n ti tún gba àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàijírìa nímọ̀ràn láti lo ànfàní ìmọ̀ ẹ̀rọ lọ́nà tó tọ́ àti fún ìdàgbàsókè.

Ìmọ̀ràn náà kò sẹ̀yìn bí ìròyìn tí kò lẹ́sẹ̀-ń-lẹ̀ àti ọ̀rọ̀ àsàsàmọ̀sì se di tọ́rọ́-fọ́n-kálé ní ilẹ́ẹ̀ Nàijírìa.

Alákoso ètò ìròyìn Àlhájì Lai Mohammed ló mú ọ̀rọ̀ ìyànjú náà wa nígbà tó ń kópa lórí ètò ilé isẹ́ Radio Nàijirìa àpapọ̀ kan l’Abuja laarọ yi.

Àlhájì Mohammed rọ àwọn ọmọ ilẹ́ẹ̀ Nàijírìa láti ka àsà wíwàdí ohun gbogbo dájú kí wọ́n tó ma tan ìròyìn tí wọ́n bá gbọ́ kale.

Ó ní ìjì fífi ẹgbẹ́ òsèlú kan sílẹ̀ lọ sí òmíràn tó ńfẹ́ kíì se nítorí ẹ̀sùn tí àwọn kan fi kan pé, àìse ìjọba dáradára ló sokùnfà-a-rẹ̀.

Àlhájì Mohammed tó tọ́ka sí àwọn àseyọ́rí Àarẹ Buhari satótónu pé, ìgbé ayé àláafìa jẹ ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn ilẹ̀ Náijírìa àti pé, kí oníkálùkù sa ipa tirẹ̀ fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè.

Ayankọsọ

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *