Akọ̀wé tẹ́lẹ̀ fun jọba àpapọ̀ gbóríyìn fádelé Ààrẹ

Senato Adeleke: Ilé ẹjọ́ gíga wọ́gilé ẹ̀sùn ìwé-ẹ̀rí
August 8, 2018
Embracing Life Planning To Discourage Teenage Pregnancy
August 8, 2018
Akọ̀wé tẹ́lẹ̀ fun jọba àpapọ̀ gbóríyìn fádelé Ààrẹ

Akọ̀wé tẹ́lẹ̀ síjọba àpapọ̀ orílẹ̀dè yíì, Olóyè Olu Falae ti sàpèjúwe ìgbésẹ̀ bíwọ́n se ní kí olùdarí àgbà pátápátá fẹ́ka ilé-isẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, DSS, ọ̀gbẹ́ni Lawal Daura lọ rọ́kún nílé, gẹ́gẹ́ bí èyí tó se àtẹ̀wọ́gbà, tó sì rọ àwọn ọ̀gá àgbà àjọ alaabo tókù, láti jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nídi isẹ́ tíwọ́n yàn lááyo.

Olóyè Falae, tọ́kasi pé, ìgbésẹ̀ tí olùdarí àgbà ilé-isẹ́ atẹlẹ̀múyẹ́ gbé ọ̀hún, fihàn pé, ó yẹ lẹ́ni tíwọ́n ń yọ kúrò nípò.

Ó wá gbóríyìn fádelé Ààrẹ ilẹ̀ yiì, ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọsinbajo fún bó se jẹ́ akọ́sẹ́mọsẹ́ nídi isẹ́ tó yàn lááyo nídi gbígba orílẹ̀èdè yíì kalẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ìwà ìdọ̀tí tó se e se kó tún súyọ lọ́jọ́ iwájú.

Kò sài tún fìrètí hàn pé, ìgbésẹ̀ àjọ aláabo tó kù lọ́gbọ́n, lákokò tíwan bá fẹ́ máà yanjú àwọn ọ̀rọ̀ tóníse pẹ̀lú ọ̀rọ̀ òsèlú nílẹ̀ yíì.

Adegbite/Wojuade

 

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *