Senato Adeleke: Ilé ẹjọ́ gíga wọ́gilé ẹ̀sùn ìwé-ẹ̀rí

Àarẹ ilé ìgbìmọ̀ Asòfin àgbà gbóríyìn fún Adele Àarẹ
August 8, 2018
Akọ̀wé tẹ́lẹ̀ fun jọba àpapọ̀ gbóríyìn fádelé Ààrẹ
August 8, 2018
Senato Adeleke: Ilé ẹjọ́ gíga wọ́gilé ẹ̀sùn ìwé-ẹ̀rí

Ilé ẹjọ́ gíga Ìpínlẹ̀ Ọsun wọ́gilé ẹ̀sùn ìwé-ẹ̀rí ayédèrú táwọn kan fikan olúdíje fún ipò Gómìnà, lábẹ́ òsèlù PDP, fún tètò ìdìbò tí yóò wáyé lọ́jọ́ kejìlélógún osù kẹsan, Ṣẹnatọ Ademọla Adeleke.

Onídajọ́ David Ọladimeji ló gbédajọ́ náà kalẹ̀ láárọ òní, pẹ̀lú àlàyé pé, ẹ̀rí tówà níwájú ilé-ẹjọ́ náà fihàn pé, olùdíje táwọn olùpẹ̀jọ́ náà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ìwé ẹ̀rí máà jẹ́mi nìsó, tíwọ́n fi ti ìpẹ̀jọ́ wọn nídi.

Méjì nínú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú PDP, nípínlẹ̀ ọ̀sun, ọ̀gbẹ́ni Rsheed Olabayọ àti Idowu Oluwaseun ló fẹ̀sùn kan Ṣẹnatọ Adeleke pé, kò ní àwọn ìwé-ẹ̀rí tó kójú òsùwọ̀n to, láti díje.

Adájọ́ Ọladimeji sọpé, lootọ làwọn pàsípayọ kan wà, lórí ìwé-ẹ̀rí olùjẹ̀jọ́, sùgbọ́n àwọn olùpẹ̀jẹ̀jọ́ kò fi eléyi kún ìwé ẹ̀sùn tíwọ́n kọ, tó lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, níse ni olùdíje náà se àtọwọ́dáìwé-ẹ̀rí.

Akinola/Wojuade

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *