Ilé-isẹ́ ọlọ́pa kó àwọn ọlọ́pa lọ sí Ìpínlẹ̀ Ọsun

Ètò àríyànjiyàn fáwọn olùdíje sípò Gómìnà nípínlẹ̀ ọ̀sun ńlọ lọ́wọ́
September 12, 2018
Sẹnatọ Abiọla Ajimọbi gbàwọn olùdíje nímọ̀ràn
September 12, 2018
Ilé-isẹ́ ọlọ́pa kó àwọn ọlọ́pa lọ sí Ìpínlẹ̀ Ọsun

Sáajú ètò ìdìbò sípò Gómìnà ti yóò wáyé nípínlẹ̀ Ọsun, ilé-isẹ́ ọlọ́pa ilẹ̀ yíì ti kó àwọn òsìsẹ́ ọlọ́pa tó ńbẹ nípínlẹ̀ náà lọ sáwọn ibi tó se kókó láti máà finúnfínlẹ̀ lórí àwọn olósèlú kan, tó se ése kíwọ́n máà fowó ra ẹ̀rí ọkàn àwọn olùdìbò.

Olórí ẹ̀ka tó ńgbàròyé aráalu nílesẹ́ ọlọ́pa náà, ọ̀gbẹ́ni Abayọmi Shogunlẹ ló fìdí èyí múlẹ̀ nílu Osogbo lákókò àbẹ̀wò rẹ̀ síbùdó ẹgbẹ́ àwọn oníròyìn tó wà nípínlẹ̀ Ọsun, tó sì ke sáwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Ọsun láti wá jábọ̀ èyíkèyí òsìsẹ́ ọlọ́pa tó bá ń gbẹ̀yìn bẹbọ jẹ́ tàbí tàpá sétò ọmọnìyàn sáajú lákókò, àti lẹ́yìn tétò ìdìbò náà bá tún parí tan, nítorí pé, ilé-isẹ́ ọlọ́pa náà ti setán láti yọ àwọn kànda kúrò nínú ìrẹsì nílesẹ́ ọ̀hún.

Ọgbẹni Shogunlẹ wa sọ́ọ̀di mímọ̀ pe, ilé-isẹ́ náà kóun sisẹ́ féyikéyi olósèlú tàbí olùdíje kankan lákókò ètò ìdìbò ọ̀hún.

Net/Fọlakẹmi Wojuade

 

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *