A kì se agbẹnusọ Ìjọba nìkan – iléésẹ́ Radio Nigeria

Akòní ìpinnu láti sún ètò ìdìbò gbogbogbò síwájú – INEC
September 13, 2018
Flooding: Delta Puts SEMA, Stakeholders on Alert
September 13, 2018
A kì se agbẹnusọ Ìjọba nìkan – iléésẹ́ Radio Nigeria

Iléésẹ́ Radio Ìjọba àpapọ̀, Radio Nigeria ti mu dáà àwọn èèyàn orílẹ̀dè yi lójú pé, òun kò ní káàrẹ láti mú kí ìjọba ma jíyìn isẹ́ ìríjú rẹ̀ fún àwọn aráàlu.

Níbi ètò tí ilésẹ́ Radio Nigeria gbékalẹ̀ fún àwọn tó fẹ́ díje fún ipò Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọsun, láti sọ ohun tí wọ́n ó se fún’lu, ni ọ̀gá àgbà iléésẹ́ Radio Nigeria lẹ́kùn Ìbàdàn, Àlhájì Mohamed Bello ti sàlàyé pé, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni ma lérò pé ìjọba nìkan ni Radio Nigeria ńgbẹ nusọọ, nítorípé ìjọba ló níì.

Àlhájì  Bello sàlàyé síwájú pé, toripé owó orí tí àwọn aráàlu ń san ni wọ́n fi gbé iléésẹ́ nà róò, ó pọndandan láti ma gbẹnusọ fún àwọn tí ohùn wọn kò jákè.

Àwọn olùdíje fún ipò Gómìnà Ọsun nà wá sèlérí láti mú ọ̀rọ̀ ìgbáyégbádùn àwọn aráálu lọ́kunkúdùn pẹ̀lú ìpèsè àwọn ohun amáyédẹrùn sílubí wọ́n bá dìbò yàn wọ́n.

Adenitan /Akinsọla

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *