Akòní ìpinnu láti sún ètò ìdìbò gbogbogbò síwájú – INEC

Owó osù tuntun: Ẹgbẹ́ Osisẹ́ Fún Ìjọba Àpapọ ní Gbèdéke
September 13, 2018
A kì se agbẹnusọ Ìjọba nìkan – iléésẹ́ Radio Nigeria
September 13, 2018
Akòní ìpinnu láti sún ètò ìdìbò gbogbogbò síwájú – INEC

Àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀èdè yi, INEC, ti sọ pé, kò sí óòtọ nínú àhesọ ọ̀rọ̀ pé, àjọ na fẹ́ sún ètò ìdìbò gbogbogbò tó yẹ kó wáyé lọ́dún tó ńbọ̀ síwájú.

Àtẹ̀jáde látọ̀dọ̀ alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu sàlàyé pé, ohun tí òun ń sọ ni pé, ìwé òfin ètò ìdìbò orílẹ̀èdè yi, sọ pé, ó se pàtàkì kíì álááfìa ó jọba nílu kí gbogbogbò ǹkan si máà lọ létòlétò kó tó di ọjọ́ ìdìbò, lásìkò ìdìbò àti lẹ́yìn ìgbà na àti pé, ó se kókó kí àjọ elétò ìdìbò na ma sisẹ́ papọ̀ pẹ̀lú àwọn elétò ààbò.

Alága àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀èdè tún tọ́ka si pé, olósèlú kan ń sọ̀rọ̀ kòbàkùngbé àti èyí tó lè dàlúrú.

Ó wá kéésí àwọn àjọ elétò ààbò lórílẹ̀èdè yi láti tètè gbé ìgbésẹ̀ lórí àwọn ǹkan tó fẹ́ da họ́hù họ́hù sílẹ̀ náà.

Net/Fọlasade Osigwe

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *