Owó osù tuntun: Ẹgbẹ́ Osisẹ́ Fún Ìjọba Àpapọ ní Gbèdéke

Wonders of Creation: Snub-nosed Monkey
September 13, 2018
Akòní ìpinnu láti sún ètò ìdìbò gbogbogbò síwájú – INEC
September 13, 2018
Owó osù tuntun: Ẹgbẹ́ Osisẹ́ Fún Ìjọba Àpapọ ní Gbèdéke

Àwọn olórí ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ti sọfún ìjọba àpapọ̀ pe ko fíì ọ̀rọ̀ owó osù tuntun tí wọ́n fẹ́ ma san fún àwọn òsìsẹ́ falẹ̀, bí kòbá fẹ́ kí àwọn òsìsẹ́ fárígá.

Àwọn olórí ẹgbẹ́ òsìsẹ́ na tí wọ́n sọ̀rọ̀ yi nílu Èkó, sọ pé ọjọ́ mẹ́rìnlá làwọn fún ìjọba àpapọ̀ láti firíì dájú pé, ìgbìmọ̀ tó ń sisẹ́ lórí ọ̀rọ̀ owó osù tuntun na parí isẹ́ lórí ọ̀rọ̀ náà.

Àarẹ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ lórílẹ̀èdè yi NLC, ọ̀gbẹ́ni Ayuba Wabba só pé, nínú ìgbìmọ̀ na kò dùn sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ní alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ àti bọ́wọ́ isẹ́ se ńyá síì Dókítà Chris Ngige, sọ́ọ̀.

Níbàyíná, ọ́fìsì àarẹ tí fi àwọn òsìsẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé, ìjọba àarẹ Muhamadu Buhari yo fikùn owó osù àwọn òsìsẹ́.

Olùrànlọ́wọ́ pàtàkì sí àarẹ lórí ọ̀rọ̀ tó kan ilé ìgbìmọ̀ asòfin àpapọ̀ sẹnatọ Ita Enang, ló sọ̀rọ̀ ìdánilógú na lẹ́yìn tí àwọn kan tí n sọ pé, ó dàabí pé ìjọba àpapọ̀ kò setán àti fikún owó osù tó kéréjù.

Net/Fọlasade Osigwe

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *