Ẹgbẹ Afẹnifẹre nfẹ ki wọn Gbaṣẹ lọwọ awọn Oga Oṣiṣẹ Alabo

Safe Driving in the “Ember” Months
November 28, 2018
Super Falcons Kogoja lati Kopa Ninu Aṣekagba Idije Ife Ẹyẹ Agbaye
November 28, 2018
Ẹgbẹ Afẹnifẹre nfẹ ki wọn Gbaṣẹ lọwọ awọn Oga Oṣiṣẹ Alabo

Ẹgbẹ Afẹnifẹre  ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati jawe ile fun gbogbo awọn ọga oṣiṣẹ eleto aabo latari iṣẹlẹ pipa awọn ọmọ oloogun bii ọgọrun latọwọ ikọ Boko Haram nipinlẹ Borno.

Nigba to nka iwe afẹnukọ ipade ẹgbẹ  naa to waye ni Akure, nipinlẹ Ondo, Akọwe iponlongo ẹgbẹ Yinka Odumakin kọminu lori iṣẹ kupani awọn ọmọ oloogun pẹlu obitibiti biliọnu Naira ti ijọba fi sita lati gbogun ti igbesunmọmi.

Ẹgbẹ Afẹnifẹre tun kọminu lori iṣẹlẹ ijinigbe to nwaye gbọnmọgbonmọ lapa guusu lọwọ ooru nilẹ wa paapa julọ ipinlẹ Ondo.

Kẹmi Ogunkọla

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *