Ìjọba Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ sọ kọ́kọ́rọ́ sẹ́nu ọ̀nà ilé ẹ́kọ́ girama kan

FIFA Selects Referees for Women’s World Cup
December 4, 2018
Ìjọba Àpapọ̀ gbé ìgbésẹ̀ akin lórí ríra ohun ìjà ogun
December 4, 2018
Ìjọba Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ sọ kọ́kọ́rọ́ sẹ́nu ọ̀nà ilé ẹ́kọ́ girama kan

Ìjọba Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ titi ilé ẹ̀kọ́ girama ti ìjọba tó wà lágbègbè Olódó ní ìlú Ìbàdàn pa lẹ́yẹ ò sọkà.

Àtẹ́jáde kan tí adelé ọ́gá àgbà ilé isẹ́ ètò ẹ̀kọ́ Arábìnrin Ibironkẹ Fatoki fi síta, sàlàyé pé, ìgbésẹ̀ náà kò sẹ̀yìn bí àwọn ìsọta kan se dáná sun ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún nígbà tí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà kan tó wà ni ìpele àkọ́kọ́ dá yánpọnyánrin sílẹ̀.

Arábìnrin Fatoki sọ pé, ìjọba ti gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni-mẹ́fà dìde láti se ìwádi ohun tó fa họ́hù-họ́hù náà, àti pé wọ́n ńretí àbọ̀ ìwádi wọn lẹ́yìn ọjọ isẹ́ méje.

Ó sàlàyé pé yàrá ìkẹ́kọ mẹ́ta àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mẹ́rin ni wọ́n dáná sun tí wọ́n sì dá ẹ́mì ẹnìkan légbodò lákokò rúkerùdò ọlọ́jọ́ méjì náà.

Kẹmi Ogunkọla/Ayankọsọ

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *