Igbákejì Àarẹ kọminú lórí báwọn èèyàn se ńpọ̀si lórólẹ̀-èdè yi

2019: Nigeria Police Strategizes to Ensure Credible Poll
December 5, 2018
Ìjọba Àpapọ̀ fi gbèdéke lélẹ̀ lórí píparí isẹ́ ọkọ̀ ojú irin ilẹ̀ èkósí Ìbàdàn
December 5, 2018
Igbákejì Àarẹ kọminú lórí báwọn èèyàn se ńpọ̀si lórólẹ̀-èdè yi

Igbákejì Àarẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọsinbajo sọ pé, báwọn èèyàn se ńpọ̀si lórílẹ̀-èdè yíì lè sokùnfà ìpèníjà fúnlẹ̀ Nàijírìa nígbà ta abá firí ọdún 2030.

Níbi ìsíde ayẹyẹ àpérò ìfètòsọ́mọbíbí nílẹ̀ yíì, ẹlẹ́karun irú ẹ̀, tó ńlọ lọ́wọ́ nílu Abuja, lọ̀jọ̀gbọ́n Ọsinbajo to sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀, pẹ̀lú àtọ́kasí pé, ìsèjọba tó kọjá lọ kòní àwọn ohun àmúyẹ tótó fún àlànà ìfètòsọ́mọbíbí àwọn Obìnrin tó wà lọ́wọ́ ìbímọ.

Igbákejì Àarẹ kò sài sọ́ọ̀di mímọ̀ pé, nínawọ́ tó jọjú sẹ́ka ètò ìfètòsọ́mọbíbí lábẹ́ ìsàkóso Àarẹ Muhammọdu Buhari ti kógojá, tọ́wọ́ rẹ̀ kò sì tún gunpá, bẹ́ẹ̀ ló si ńdàbòbò ẹ̀mí àwọn èèyàn.

Ó sàlàyé pé, béròngbà ìdàgbàsókè sáà tawàyíì yóò bawa símùsẹ, títí ọdún 2030, yóò lọ́wọ́ bíwọ́n bá sì mọ́rọ̀ ìfètòsọ́mọbíbí àtẹ̀tọ́ àwọn Obìnrin lọ́kunkúdùn.

Kẹmi Ogunkọla/Net

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *