Ìjọba Àpapọ̀ fi gbèdéke lélẹ̀ lórí píparí isẹ́ ọkọ̀ ojú irin ilẹ̀ èkósí Ìbàdàn

Igbákejì Àarẹ kọminú lórí báwọn èèyàn se ńpọ̀si lórólẹ̀-èdè yi
December 5, 2018
National Sports Festival: Ondo Athletes Set for better Performance
December 5, 2018
Ìjọba Àpapọ̀ fi gbèdéke lélẹ̀ lórí píparí isẹ́ ọkọ̀ ojú irin ilẹ̀ èkósí Ìbàdàn

Ìjọba àpapọ̀ ti fi gbèdéke titun lélẹ̀ lórí àsepárí isẹ́ àkànse ojú ọ̀nà ọkọ̀ ojú-irin Èkó sí Ìbàdàn tolódiwọ̀n ìgbàlódé, èyí tóyẹ kísẹ́ parí lórí rẹ̀ lósù yíì.

Alákoso fétò ìrìnà, ọ̀gbẹ́ni Rotimi Amaechi, ẹnitó tó ń sàbẹ̀wò olósosù rẹ̀ lórí àkànse bílliọnu kan àbọ̀ dọllar lé diẹ sọpé isẹ́ àkànse náà yóò parí lósù kejì ọdún tó ńbọ̀.

Ojú-ọ̀nà ọkọ̀ ojúirin Èkó sí Ìbàdàn tolódinwọ̀n ìgbàlódé náà jẹ́ isẹ́ kìlòmítà mẹ́rìndínlọ́gajọ pẹ̀lú ibùdókọ̀ ojú irin ìgbàlódé mẹ́wa àti àwọn afárá.

Ọgbẹni Amechi sọpé gbogbo ìgbésẹ̀ ló ti ńjẹ́ gbígbé láti ridájú pé, ojú ọ̀nà ọkọ̀ ojúrin olódowọ̀n ìgbàlódé ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ isẹ́ láti Èkó sí Abẹ́okúta tíki báà se sí Ìbàdàn lósù kejì ọdún tó ńbọ̀.

Kẹmi Ogunkọla/Net

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *