Ilésẹ́ Epo Rọ̀ọ̀bì Nílẹ̀yí Ṣèlérí láti mú Képo Pọ̀ Yanturu

Drama: Destitute Slug it out over Space in Ekiti
December 6, 2018
Recent Reductions of Examinations Fees by Federal Government
December 6, 2018
Ilésẹ́ Epo Rọ̀ọ̀bì Nílẹ̀yí Ṣèlérí láti mú Képo Pọ̀ Yanturu

Ilésẹ́ tón rísí epo rọ̀ọ̀bì nílẹ̀yí, NNPC, ti se ìlérí láti mú képo rọ̀ọ̀bì pọ̀ yanturu, yíká orílẹ̀èdè yi.

Ọga’gbà fún ilésẹ́ ọ̀hún, Díkítà Maikanti Baru ló sọ̀rọ̀ yi lásìkò táwọn ilé ìgbìmọ̀ asòfin tón rísí ẹ̀ka epo rọ̀ọ̀bì lọ se àbẹ̀wò ẹkúsẹ́ ńbẹun sí olúlesẹ́ epo rọ̀ọ̀bì tó wà l’Abuja.

Ó fi ọkàn àwọn èyàn ilẹ̀ yi balẹ̀ wípé ilésẹ́ náà ti gbaradì láti ridájú pé epo rọ̀ọ̀bì wà fún lílò àwọn èyàn ilẹ̀ yi lásìkò ọdún àti lkyìn rẹ̀.

Alága ilé ìgbìmọ̀ tẹ̀kótó ilé ìgbìmọ̀ asòfin kejì lórí ọ̀rọ̀ epo rọ̀ọ̀bì, ọ̀gbẹ́ni Joseph Akinlaja rọ ilésẹ́ tón rísí epo rọ̀ọ̀bì láti ri dájú pé àwọn èyàn ilẹ̀yi tó fẹ́ rìnrìnàjò lásìkò ọdún lọ láisi wàhálà kankan.

Ọgbẹni Akinlaja wá gbóríyìn fún akitiyan ilésẹ́ yi láti mú képo wà lárọwọ́tó àwọn èyàn ilẹ̀ yi.

Láipẹ yi ni àwọn alágbàtà epo bẹntirol sọ pé, àwọn yo gbé gbogbo ibùdó ìgbọ́npo tìpa, tí ìjọba bá kọ́ láti san owó ìrànwọ́ fún wọn.

Kẹmi Ogunkọla/Net

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *