Àgbáríjópọ̀ Ẹgbẹ́ Òsìsẹ́ Gùnlé Ìfẹ̀hónúhàn lórí Ọ̀rọ̀ Owó Oṣù Tuntun

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ Pèfún Gbígbé ní Ìrẹ́pọ̀
January 8, 2019
Ekiti NUJ Prays for National Peace
January 8, 2019
Àgbáríjópọ̀ Ẹgbẹ́ Òsìsẹ́ Gùnlé Ìfẹ̀hónúhàn lórí Ọ̀rọ̀ Owó Oṣù Tuntun

Ìwosẹ́ níran àwọn òsìsẹ́ nílẹ̀ Nàijírìa tó bẹ̀rẹ̀ lórí bíjọba àpapọ̀ se kùnà láti gbé àbá fún sísan ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n naira gẹ́gẹ́bí owó osù tó kéré jù síwájú àwọn ilé asòfin àpapọ̀, àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ gùnlé ìfẹ̀họ́núhàn yíká orílẹ̀-èdè Nàijírìa láti lè kanpa fún Ijọba láti gbé ìgbésẹ̀ tó yẹ.

Nígbà tón sọ̀rọ̀ lórí ìfẹ̀họ́núhàn tó ńlọ lọ́wọ́, akọ̀wé àgbà, fẹ́gbẹ́ òsìsẹ́ Dókítà Peter Ozo-Eson, sọ wípé àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ní Ìpínlẹ̀ mẹ́rindínlógójì tó wà nílẹ̀ yi ló nkanpa nínú ìfẹ́họ́núhàn náà.

Níbàyínáà, ìpàdé àwọn ẹgbẹ́ òsìsẹ́ láti dènà, ìdúnmọ̀huru mọ́ni lórí kíkùnà láti gbé àbá, lórí owó osù tuntun lọsíwájú ilé asòfin àpapọ̀ ni yo tún wáyé lọ́jọ́ ìsẹ́gun tó ńbọ̀.

Alákoso fọ́rọ̀ isẹ́ àti ìgbanisísẹ́ Sẹ́nétọ̀ Chris Ngige ló sọ̀rọ̀ yi fáwọn akọ̀ròyìn lẹ́yìn ìpàdé àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ òsìsẹ́ tó wáyé nílu Abuja.

Afọnja/Net

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *