Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ Pèfún Gbígbé ní Ìrẹ́pọ̀

Oyo Labour Unions Demand Implementation of Minimum Wage
January 8, 2019
Àgbáríjópọ̀ Ẹgbẹ́ Òsìsẹ́ Gùnlé Ìfẹ̀hónúhàn lórí Ọ̀rọ̀ Owó Oṣù Tuntun
January 8, 2019

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ ti jẹ́jẹ láti dèná irúfẹ́ rógbòdìyàn tó wáyé láipẹ yi nílu ’bàdàn, níbití ǹkan ni tótó ọ̀pọ̀lọpọ̀ milliọnu naira níye ti sọnù.

Gómìnà Ìpínlẹ̀ yi, Sẹnatọ Abiọla Ajimọbi ló sọ̀rọ̀ ìdánilógú yi, lásìkò tó lọ se àbẹ̀wò sí ibi tí ìsẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, láwọn agbègbè bíì, Ìdí Arẹrẹ, Fọ̀kọ̀ tó fidé Agúgù.

Gómìnà, ẹnití igbákejì Gómìnà, Olóyè Moses Adeyẹmọ soojú fún, fi àidùnnú rẹ̀ hàn lórí báwọn ǹkan ìní se bàjẹ́, ló wá sọ wípé àwọn èyàn Ìpínlẹ̀ Ọyọ gbọdọ̀ ma gbé nírẹpọ̀ pẹ̀lú ẹnìkejì wọn.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ alákoso ilé isẹ́ ọlọ́pa nípinlẹ̀ Ọyọ, ọ̀gbẹ́ni Abiọdun Odude sọ pé ilẹ́sé ọlọ́pa yo túsu dé ìsàlẹ̀ kòkò lórí ọ̀rọ̀ ọ̀hún.

Àwọn tó lùgbàdì ìsẹ̀lẹ̀ náà, sáláyé pé àwọn oníjágídíjàgan kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan ìní wọn lọ, tí kò dí ní ọ̀pọ́ọ̀ milliọnu naira níye.

Makinde/Afọnja

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *