Ìpínlẹ̀ Èkìtì Fọwọ́sí Àsùnwọ̀n kan soso tí Wọ́n ó ma Sanwó Sí fún Ìjọba

Ìjọba Àpapọ̀ yo sọ Àsọyán lórí Owó Osù Tuntun
January 10, 2019
Don’t give Room for Inconclusive Election- INEC
January 10, 2019
Ìpínlẹ̀ Èkìtì Fọwọ́sí Àsùnwọ̀n kan soso tí Wọ́n ó ma Sanwó Sí fún Ìjọba

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkìtì ti fọwọ́sí sísàmúlò àsùnwọ̀n ẹyọkan soso tí wọ́n yo ma sanwó Ìjọba sí, láti lè fòpin sí báwọn kan se ń jí owó ìjọba, àti wípé kámogbòrò lèdébá fífi òotọ́nú sètò ìjọba.

Ìgbésẹ̀ náà jẹ́, èyí tí wọ́n fẹnukò lé lórí níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ alásẹ tó ma ńwáyé lọ́sọ̀sẹ̀ l’ádó Èkìtì, èyí tí Gómìnà Kayọde Fayẹmi léwájú rẹ̀.

Akọ̀wé ìròyìn fún Gómìnà, ọ̀gbẹ́ni Yinka Oyebọde tó jẹ́ kéyi di mímọ̀, níbi ìpàdé oníròyìn sàlàyé pé, ní kọ́mọ́nkía ni ilésẹ́ tó ńrísí ètò ìsúná, àti tagbẹjọ́rò àgbà yo bẹ̀rẹ̀ sísàmúlò àsùnwọ̀n ẹyọkan soso.

Ọgbẹni Oyebode fikun pé, ìgbìmọ̀ náà ti fọwọ́sí ọ̀dúnrún dín ládọta milliọnu naira gẹ̀gẹ̀bí owó tí wọ́n yo máà sétò ẹ̀kọ́ àti ẹ̀ka ètò ìlera láwọn agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́rin, eyun ni Ọyẹ, Moba, Ijero àti ẹkùn ìwọ̀ orùn gúsù Èkìtì .

Ó tọ́kasi pé, owó ọ̀hún ni wọn yó lò láti lè rí ẹdẹgbẹta milliọnu naira gbà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ètò tó fi ẹsẹ̀ ìdàgbàsókè ọdún 2018 múlẹ̀ láti le mú àgbéga bá Ìpínlẹ̀ Èkìtì.

Afọnja/Net

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *