Ilé asòfin se atótónu lórí ìgbógúnti ìwà àjẹbánu

Gómìnà Makinde pèfún àdúrà lórí ìfẹsẹ̀múlẹ̀ àlááfìa
July 18, 2019
Oyo Assembly Forms Standing Committees
July 18, 2019
Ilé asòfin se atótónu lórí ìgbógúnti ìwà àjẹbánu

Ilé asòfin àgbà orílẹ̀èdè yíì sọpé óse pàtàkì, korò ìwà àjẹbánu lẹ́ka ètò ìdájọ́ jẹ́ wíwá ojútu sí.

Adarí ilé, Ahmed Lawan sọ̀rọ̀ yíì lákokò tí wọ́n fìdí ìyànsípò onídajọ́ Mohammed Tanko múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ àgbà ilẹ̀ Nàijírìa.

Àwọn asòfin náà fìdirẹ̀ múlẹ̀ pe, ìwà àjẹbánu náà ńwàyé lẹ́ka ètò ìdájọ́.

Nígbà tó ń fèèsì, sáwọn ìbére táwọn asòfin ńbèrè fun, adájọ́ Mohammed Tanko, wá bèrè fún ìjìyà kana fáwọn adájọ́ táje ìwà ìbàjẹ́ bá símọ́ lóorí àtàwọn èèyàn àwùjọ min, láti kọ́ àwọn èèyàn àwùjọ tóòku lọ́gbọ́n.

Onídajọ́ Muhammed, ẹni tó gbà pé lóòtọ níwà-ìbàjẹ́ wà lẹ́ka ètò ìdájọ́, tó sì dẹ̀bi ìwà àjẹbánu rúù àisí ìjìyà tó gbópọn fáwọn tó ńwùwù-ìbàjẹ̀.

Onídajọ́ Muhammed kò sài wá késí asòfin àgbà àtàwọn asòfin ìpínlẹ̀ láti sàtúngbéyẹ̀wò àwọn òfin tóníse pẹ̀lú ìjìyà ìwà àjẹbánu àtàwọn tó ńlọ́wọ́ nínú ìwà ọ̀daràn.

Kẹmi Ogunkọla/Alamu

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *