Àjọ elétò ìdìbò fí àtẹ ìlànà ìdìbò síta.

Ìpínlẹ̀ Òndó gbé ìgbésẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ ìdaranjẹ̀
January 11, 2018
News Analysis: Expert Articulates Solution to Herdsmen’s Killing
January 11, 2018
Àjọ elétò ìdìbò fí àtẹ ìlànà ìdìbò síta.

Àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ yíì, INEC, tí fi àtẹ ìlànà àtéétò gbogbo fétò ìdìbò gbogbobgò ọdún 2019 yóò se lọ síta.

Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood Yakubu, ló fìdí èyí mulẹ̀ níbi àpérò àwọn oníròyìn tó wáyé nílu Abuja.

Ó sàlàyé pé, tó bá di ọjọ́ kẹtàdínlógún osù kẹ́jọ, ọdún tawàyí lọ́jọ́ náà yóò jẹ́ káwọn aráálu náà mọ̀, bétò ìdìbò yóò se lọ gan-gan níbamu pẹ̀lú òfin ètò ìdìbò ọdún 2010.

Kò sài fikun pé, ìwé òfin náà sọ́ọ́di mímọ̀ pé, àadọ́rin ọjọ́ kó to dakoko ètò ìdìbò niwọ́n gbọdọ̀ jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ bátò ìdìbò yóò se lọ.

Ọjọgbọn Yakubu tún fikun pé, ètò ìdìbò abẹ́nú àwọn ẹgbẹ́ òsèlú àti yíyanjú àwọn kùdìẹ-kudiẹ yóò wáyé laarin ọjọ́ kejìdínlógún osù kẹ́jọ sọ̀jọ̀ kéje osù kẹwa, ọdún 2018, tó si sọpé gbogbo àwọn ẹgbẹ́ òsèlú náà ló ti gbọdọ̀ gba fọ́ọ́mu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọlé, ó pẹ́jù ọjọ́ kérìnlélógún osù kẹjọ ọdún tawàà yíì.

Ogunkọla

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *