Ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára gbìnàyá ńpínlẹ̀ ọ̀yọ́

Nine Communities Benefit from Development Projects in Ekiti
January 11, 2018
Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ gbé ìgbésẹ̀ akin lórí ìmọ̀tótó
January 12, 2018
Ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára gbìnàyá ńpínlẹ̀ ọ̀yọ́

Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ yo bẹ̀rẹ̀ fífín àwọn ọmọ tọ́jọ́ orí wọ́n wà lábẹ́ ọdún márun ní abẹ́rẹ́ àjẹsára Vitamin A tí yó si wa sópin ní ọjọ́ kejìlá osù yíì.

Alákoso fétò ìlera nípínlẹ̀ ọ̀yọ́ Dókítà Azeez Adeduntan ló jẹ́ kéyi di mímọ̀ fáwọn oníròyìn nílu ìbàdàn.

Ó sàlàyé pé, gbígba èròjà afáralókun Vitamin A yí, yó mú àmúgbòrò bá ìlera láti dénà àrùn ìgbóná àti wípé yó mú kójú ọmọ rínaa kedere.

Dókítà Adeduntan sàlàyé pé, ètò náà yọ wáyé yíká gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ nípínlẹ̀ yí, táwọn òsìsẹ́ elétò ìlera yó si tún lọ yíká gbogbo iléwe tó wà nípínlẹ̀ yíì káwọn ọmọ wẹrẹ le jẹ ànfàní ètò náà.

Ó wá rọ àwọn òbí àtalágbàtọ́ láti rí dájú pé, àwọn ọmọ wọ́n jẹ ànfàní gbígba abẹ́rẹ́ àjẹsára Vitamin A yíì, kí wọ́n sí kó àwọn ọmọ wọ́n lọ sí iléwòsàn àti gbogbo ibùdó tíjọba ti sètò rl sílẹ̀ fún ètò ọ̀hún.

Ogunkọla/Makinde

 

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *