Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ gbé ìgbésẹ̀ akin lórí ìmọ̀tótó

Ètò abẹ́rẹ́ àjẹsára gbìnàyá ńpínlẹ̀ ọ̀yọ́
January 12, 2018
No Immediate Solution to Fuel Scarcity- Ondo DPR
January 12, 2018
Ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ gbé ìgbésẹ̀ akin lórí ìmọ̀tótó

Tó ba dọjọ́ ajé Monday ọ̀sẹ̀ tó ńbọ̀, nìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ lòun yóò bẹ̀rẹ̀ ètò àyẹ̀wò ilé-sílé láti mọ ibi táwọn èèyàn wọ́n ńdalẹ̀ wọ́n sí.

Ètò àyẹ̀wò náà tíwọ́n pé ní “Operation Show your Wast bin’’ ní wọ́n gbékalẹ̀ láti dènà báwọn èèyàn kan se máà n dalẹ̀ láibìkítà sáwọn ojú ọ̀nà ńláńlá tó ńbẹ nípínlẹ̀ yíì.

Nígbà tó ń báwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, alákoso fọ́rọ̀ àyíká àtàwọn ohun àlùmọ́nì inú omi, nípínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Isaac Ishola, sàlàyè pé, míma dalẹ̀ tàbí ju ìdọ̀tí láibìkítà ta ko òfin ìmọ́tótó àyíká.

Ó wá tọ́kasi pé, ilé yówù tí kó bá ní gooro ìdalẹ̀ sí lẹ́yìn àyẹ̀wò wọn yóò fún ní gbèdéke ọjọ́ mẹ́ta láti sàtúnse láise bẹ́ẹ̀ ilé-náà yóò jẹ́ títìpa tàbí sísanwó ìtanràn ẹgbẹ̀rúnlọ́nà ààdọ́ta naira, bí bẹ́ẹ́kọ kó fẹ̀wọ̀n osù mẹ́ta jura.

Ogunkọla

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *