Iléésẹ́ Ológun sèlérí ààbò tó gbópọn fáwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Ògùn

Ìjọba Àpapọ̀ ńfẹ́ kópin débá ìwà ìjínigbé lẹ́kùn Niger Delta
June 8, 2018
NBC Tasks Media on Objective Reportage
June 8, 2018
Iléésẹ́ Ológun sèlérí ààbò tó gbópọn fáwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ Ògùn

Ilé-isẹ́ ológun ilẹ̀ yíì sọ pé, digbí lòun síwa láti pèsè ètò àbò tó múná dóko fáwọn olùgbó Ìpínlẹ̀ Ògùn.

Olùdarí tuntun fẹ́kùn ọwọ́ márùndínlógógì ilé-isẹ́ ọmọ ológun náà tó wà lágbègbè Alámàlà, nílu Abẹokuta, ọ̀gágun àgbà Olusẹgun Ọlatunde ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì lákókò àbẹ̀wò àjọsèpọ̀ kan tó se sọ́dọ̀ àwọn alámojútó ẹ̀ka ilé-isẹ́ Radio Nigeria Paramount F.M, tó wà nílu Abẹokuta.

ọ̀gágun àgbà Ọlatunde tó sáláyé pé, ilé-isẹ́ ológun náà kò ní káarẹ nídi akitiyan láti máà mú àgbéga bọ́rọ̀ àláfìa àtààbò láwùjọ, tọ́ ka si pé, pàtàkì àbẹ̀wò rẹ̀ ni láti fẹsẹ̀ àjọsepọ̀ tó múná dóko mílẹ̀ pẹ̀lú ilé-isẹ́ ọ̀hún.

Nígbá tó ńfèsì, alábojútó àgbà ilé-isẹ́ ẹlẹ́rọ Amìlújìnjìn Paramount F.M, Àlhájì Adeniyi Ọdẹkunle, gbóríyìn fúnlesẹ́ ológun náà fún bó se ńpèsè ààbò bẹ nílẹ̀ yíì, tó sì sèlérí àtìlẹyìn ilé-isẹ́ náà, fún lesẹ́ ọmọ ológun ọ̀wọ́ karùndínlógójì ọ̀hún.

Kẹmi Ogunkọla/Fọlarin

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *