Ilẹ̀ gẹ́ẹ́si sèlérí àtìlẹyìn fún àserọ́yí ìdìbò Ìpínlẹ̀ Èkìtì

SON Deploys New Strategy against substandard, counterfeit products
July 13, 2018
Se bi ase pọ̀ to jẹ́ ánfàní fun orílẹ̀èdè wa?
July 13, 2018
Ilẹ̀ gẹ́ẹ́si sèlérí àtìlẹyìn fún àserọ́yí ìdìbò Ìpínlẹ̀ Èkìtì

Ìjọba ilẹ̀ gẹ́ẹ́si ti fìfẹ́hàn láti ridájú pé ètò ìdìbò sípò Gómìnà tí yóò wáyé nípínlẹ̀ Èkìtì yọrí sírere.

Alákoso àgbà nílẹ̀ gẹ́ẹ́si sílẹ̀ Nàijírìa, ọ̀gbẹ́ni Paul Arkwright ló sọ̀rọ̀ yíì di mímọ̀ lákókò àbẹ̀wò rẹ̀ sí Gómìnà Oluwarotimi Akeredolu nílu Àkúrẹ́, tí solúìlú Ìpínlẹ̀ Òndó.

ọ̀gbẹ́ni Arkwright sọ pé, ìgbìmọ̀ ilẹ̀ gẹẹsi ti fáwọn ohunwòye látilẹ̀ òkèrè sọwọ́ fétò ìdìbò náà.

Ó wá gbàwọn tọ́rọ́kàn níyànjú láti yàgò kúrò nídi màgòmágó síse lákókò ètò ìdìbò.

Kò sài fìpinu ilẹ̀ náà hàn láti pèsè isẹ́ lọ́pọ̀yanturu fáwọn ọ̀dọ́ orilẹ̀dè yíì.

Nígbà tó ńfèsì, Gómìnà Oluwarotimi Akeredolu dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn orílẹ́dè ile òkèrè fátilẹ̀yìn àseyọ́rí fétò ìdìbò sípò Gómìnà tí yóò wáyé lọ́la.

Kẹmi Ogunkọla/Dokun Ladele

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *