Ìjọba Àpapọ̀ gbé ìgbésẹ̀ lórí àmúgbòorò okòòwò

FRSC to Establish Mobile Courts in Ondo
July 18, 2018
Radio Naijiria sètò Àpérò lórí ọ̀rọ̀ Àabò
July 18, 2018
Ìjọba Àpapọ̀ gbé ìgbésẹ̀ lórí àmúgbòorò okòòwò

Kònípẹ́ táarẹ orílẹ̀dè yíì Muhammọdu Buhari yóò fi sí sọ lójú ètò kan láwọn ibùdókọ̀ ojúomi, pápákọ̀ òfurúfú àtàwọn ẹnubòdè lọ́nà àti mú kétò okòòwò rọrùn tíwọ́n yóò sì lánfàní láti máà yanjú àwọn ẹrù láarin gbèdéke àkókò wákàtí mẹ́rìnlélógún èyí ló wáyé lẹ́yìn táarẹ pàsẹ pé, kíwọ́n gbé ìlànà kan kalẹ̀ tí yóò kó gbogbo àwọn ilé-isẹ́ ìjọba tónrí sọ́rọ̀ ìwọ́lé-jáde àtọ̀rọ̀ okòòwò papọ̀ sójú kan, lọ́nà tí yóò mú ìlọsíwájú bétò àbò àtètò káràkátà.

Alákoso fétò ìrìnà, ọ̀gbẹ́ni Rotimi Amaechi, ẹnití olùdarí ilé-isẹ́ ìjọba tó ń rísí ọ̀rọ̀ìgbòkègbodò ọkọ̀ ojú omi, Sani Galandachi sojú fún, ló fìdí èyí múlẹ̀ nílu Abuja.

ọ̀gbẹ́ni Amaechi tọ́kasi pé, ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá kan tíwọ́n gbékalẹ̀, èyí tígbákejì Àarẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Ọsinbajo àtàwọn òsìsẹ́ láwọn ilé-isẹ́ àti lájọlájọ tó ń sisẹ́ láwọn ibùdó ọ̀hún niwọ́n pàsẹ fún láti máà tukọ̀ àkóso ìlànà ọ̀hún tí yóò kó gbogbo àwọn ilé-isẹ́ ìjọba papọ̀ sojú kan tí yóò sì tún mámu gbòòrò bá okòòwò ilé-isẹ́ ọkọ̀ ojú omi, tádinku yóò sì dé bá owó tíwọ́n ń ná nídi rẹ̀.

Kẹmi Ogunkọla/Kẹhinde

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *