Radio Naijiria sètò Àpérò lórí ọ̀rọ̀ Àabò

Ìjọba Àpapọ̀ gbé ìgbésẹ̀ lórí àmúgbòorò okòòwò
July 18, 2018
Controversy as Osun APC Sets for Governorship Primary
July 18, 2018
Radio Naijiria sètò Àpérò lórí ọ̀rọ̀ Àabò

Ilésẹ́-isẹ́ Radio Àpapọ̀ ilẹ̀ wa, lẹ́kùn Ìbàdàn àtilésẹ́, DEAPOJ GLOBAL NETWORK pawọ́pọ̀ se àgbékalẹ̀ àpérò ọlọ́jọ́ kan lórí ọ̀rọ̀ àabò tí yóò wáyé lọ́la òde yíì.

Ìrètí wà pé, àpérò náà làwọn Ọba Alayé àtàwọn Olórí Àwùjọ nípínlẹ̀ ọ̀yọ́yóò péjú pésẹ̀ sí láti jíròrò lórí àwọn ìpèníjà tó ń bétò ààbò ilẹ̀ yíì fínra.

Àpérò náà tí yóò wáyé ní gbọ̀ngàn Dapọ Aderọgba tó wà níbùdó àwọn Oníròyìn ládugbo ìyágankú nílu Ìbàdàn ní dédé ago mẹ́waa òwórọ̀ làwọn onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀ àabò nínú èyí tatirí, olùdarí àjọ àbò ara ẹni làbòlú Civil Defẹnce, ọ̀mọ̀wé John Adewoye àtolùdarí ilé-isẹ́ panápaná nípínlẹ̀ ọ̀yọ́, ọ̀gbẹ́ni Mọshood Adewuyi yóò péjúpésẹ̀ si.

Àgbàọ̀jẹ̀ oníròyìn títúnse àgbà àwùjọ kan, Olóyè Arẹoye Oyebọla nìrètí wà pé, òun náà yóò wà níbi àpérò ọ̀hún, nígbà tí olùdarí àgbà ilé-isẹ́ Radio Àpapọ̀ ilẹ̀ wa lẹ́kùn ‘bádàn, yóò jẹ́ olùgbàlejò àgbà.

Kéni Ogunkọla/Kẹhinde

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *