Ìpínlẹ̀ Èkó laago ìkìlọ̀ fáwọn ọlọ́kọ̀ epo

Osun SSG Decamps to ADP, Some PDP Members Protest
July 23, 2018
Àgbáríjọpọ̀ ẹgbẹ́ Oníròyìn fojú láifi wo àbádòfin lórí isẹ́ ìròyìn
July 23, 2018

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó ti fikún gbèdéke àsìkò tí wọ́n fún àwọn tó ní ọkọ̀ àjàgbé akẹ́rù àtí ọkọ̀ epo tí wọ́n wà katẹ sí ẹ̀bá ọ̀nà ní pópónà márosẹ̀ Oshodi sí Àpápá, níbàyí wọ́n tún ti fún wọn ní wákàtí méjìdínládọta kún àsìkò na.

Alákoso fétò ìrìnnà nípínlẹ̀ Èkó, ọ̀gbẹ́ni Ladi Lawanson ló kéde ọ̀rọ̀ yíì nígbà tó lọ wo ibi wọ́n bá isk déè nípa àwọn ọkọ̀ àjàgbé tí wọ́n ń gbé kúrò lẹ́ba ọ̀nà ọ̀ún.

Níbàyí ọ̀nà ti já geere dé agbègbè Mile 2, ìrètí sì wa pé, Gómìnà Akinwumi Ambọde yóò sèpàdé pẹ̀lú àwọn tọ́rọ̀ ọ̀ún kàn, láti lè wa ojútu láilái sí ìsòro na.

Nígbà tóun nà ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkọ̀ àjàgbé tí wọ́n ńkó kúrò lẹ́ba ọ̀nà ọ̀ún alákoso fọ́rọ̀ ìròyìn nípínlẹ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Kẹhinde Bamugbetan sọ pé, ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ọkọ̀ àjàgbé tí wọ́n ti gbé kúrò lójú ọ̀nà márosẹ̀ Oshodi sí Àpápá náà.

Kẹmi Ogunkọla

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *