Onímọ̀ ètò ìsúná fẹ́ káwọn ọnílésẹ́ ajé daradé ètò ìróni làgbàra ijoba

2019 Poll: Politicians Adopt Low Key Campaign in Delta
January 30, 2019
Ìpínlẹ̀ Ọsun, Kẹbbi gùnlé dídókowò nípasẹ̀ ǹkan àlùmọ́nì
January 31, 2019
Onímọ̀ ètò ìsúná fẹ́ káwọn ọnílésẹ́ ajé daradé ètò ìróni làgbàra ijoba

Àwọn olùdó kówokékèké ni wọ́n ti gbà níyànjú láti sàmúlò ètò ìrónilágbára tíjọba sẹ àgbékalẹ̀ rẹ láti mú kókowò wọn gbèrú si.

olùdarí àgbà ilé ìfowópamọ́ tó ń sagbátẹrù isẹ́ ajé arábìnrin Toyin Adeniji ló gbé ọ̀rọ̀ àmọ̀ràn yi kalẹ̀ nílu Abuja níbi ètò kan tí wọ́n se àgbékalẹ̀ rẹ̀ láti mú àmúgbòrò bá ètò ọrọ̀ ajé.

Ó sọ pé, ètò náà ti se rànwọ́ fùn àwọn olókowò kékèké, tó lé ní, milliọnu kan yíká Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndín lógójì àti olúlu Abuja.

Arábìnrin Adeniji tẹnumọ́ pé, ètò tíjọba gbé kalẹ̀ yi jẹ́ ohun ìwúrí fún àwọn olùdókòwò nílẹ̀ Nàijírìa, pẹ̀lú bí wọ́n se ń róró yá pẹ̀lú ìrọ̀rùn.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, olórí fún ètò náà, ọ̀gbẹ́ni Uzoma Nwagba tọ́kasi pé, àwọn olùdókòwò kékèké ni wọ́n kópa ìdá àdọ́ta nínú ọgọ́run, owó tón wọlé lábẹ́lé, àti ìdá ọgọ́run àwọn òsìsẹ́, pẹ̀lú àlàyé pé, olùdókòwò tó bá nífẹ láti jẹ ànfàní ètò yi gbọ́dọ̀ forúkọ sílẹ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ kan àti èyí tó jẹ́ talẹ́jẹsẹ́kù kí wọ́n sì ní ńlo ìdánimọ̀, tilé fowópamọ́ BVN, tó fimọ́ ẹ̀rọ ìbáraẹni sọ̀rọ̀.

Ilésẹ́ Radio Nigeria jábọ̀ pe, yàtọ̀ fún ètò ìrónilágbára fún àwọn olùdókòwò , ìjọba àpapọ̀ tún se ètò láti ya àwọn òntàjà onìsòwò lọ́wọ́ tí wọ́n pèní, Markẹt Mọni, Trader mọni tófimọ́ èyí tó jẹ́ tàwọn àgbẹ̀, Farmer Mọni, láti lè ran àwọn tó kudiẹ káto fún láwòjọ lọ́wọ́.

Net/Afọnja

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *