Àmọ̀ràn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ láti yàgò fún jàgìdìjàgan

Oyo PDP Assures Residents of Good Governance
February 12, 2019
Àjọ tó ńbójútó iléésẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ laago ìkìlọ̀ lórí ìdìbò tó ńbọ̀
February 13, 2019
Àmọ̀ràn lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀dọ́ láti yàgò fún jàgìdìjàgan

Wọ́n ti kìlo fáwọn sdọ́ láti máse jẹ́kí wọ́n ó lò wọ́n fún irinsẹ́ ìdàlúrú lásìkò òdìbò.

Olùdásílẹ̀ ìjọ Shafaudeen inslm kákiri àgbáyé, ọ̀jọ̀gbọ́n Sabit Ọlagike ló sọ bẹ́ẹ̀ níbi àpérò fún àwọn ọ̀dọ́ tíwọ́n pe ni ọ̀dọ́ àti ètò ìdìbò tó já gaara fọ́dún 2019 èyí tẹ́gbẹ́ àwọn tó ńrísí ètò àlááfìa àwùjọ nífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́.

Ọjọgbọn Sabit tó tún jẹ́ babasàlẹ̀ ẹgbẹ́ elétò àláafìa ẹ̀ka tìpínlẹ̀ Ọyọ rọ àwọn ọ̀dọ́ láti jẹ́ irinsẹ́ fún àyípadà rere nípasẹ̀ mímaa gùnlé àwọn ètò tó nítumọ̀.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, olùdarí àjọ olùlanilọ́yẹ̀ Ìpínlẹ̀ Ọyọ, NOA, arábìnrin Dọlapọ Dosumu tí ọ̀gágba lẹ́ka ètò gbogbo iléésẹ́ náà, ọ̀gbẹ́ni Mọshood Ọlalẹyẹ sojú fún rọ àwọn ọ̀dọ́ tíwọ́n ko wa láti ẹ̀ka ilééwe káàkiri ìlú Ìbàdàn láti tan isẹ́ ètò àláafìa àti yíyàgò fún ìbò rírà kalẹ̀.

Ẹni tó sàgbékalẹ̀ ètò náà sọ pé, wọ́n sètò ọ̀hún láti dá àwọn ọ̀dọ́ lẹ́kọ lórí ohun tó yẹ kíwọ́n se lásìkò ìbò àti lẹ́yìn ìdìbò, nígbà tíwọ́n ń fèsì àwọn ọ̀dọ́ sọ pé, ètò náà bọ́ sásìkò gáàni.

Asakẹ/Ogunkọla

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *