Àarẹ Buhari pè fún lílọ́wọ́ àwọn Ọba alayé nínú òsèlú

Ekiti Artisans to Receive Soft Loan from Government
March 6, 2019
Òjísẹ́ Ọlọ́run pè fún Ìfaraẹnijì
March 6, 2019
Àarẹ Buhari pè fún lílọ́wọ́ àwọn Ọba alayé nínú òsèlú

Àarẹ Muhammadu Buhari ti rọ àwọn Ọba alayé láti kópa tó jọjú nídi ètò àabò àti síse àwárí àwọn onísẹ́ láabi tóbá wà láyiká wọn.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ níbi ìgbàlejò àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ labalọ́ba ti Sultan ìlú Sokoto, Alhaji Muhammad Saal Abubakar kó sòdí lọ sílé ìjọba nílu Abuja, Àrẹ wòye pé, lílọ́wọ́ àwọn Ọba nídi ètò àabò se pàtàkì ta bá fẹjú wo ipa ribiribi tíwọ́n ńkó lágbègbè wọn.

Sultan ìlú Sókótó tóun náà wà lára àwọn alága ìgbìmọ̀ sọ fún Àrẹ Buhari pé, ìgbìmọ̀ náà lórúkọ gbogbo àwọn Ọba tó ń bẹ lórílẹ̀èdè yíì wá sílé ìjọba láti kí Àarẹ kúoríre àtúnyàn sípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ààrẹ orílẹ̀èdè Nàijírìa.

Lára alága ìgbìmọ̀ náà títún se Ọọni ìlú ilé Ifẹ̀, Ọba Adeyẹye Ogunwusi múdá àarẹ Buhari lójú pé, àwọn yóò sisẹ́ papọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti gbógunti ìwà ọ̀daràn.
Kemi Ogunkọla/Iyabo Adebisi

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *