Iléesẹ́ Ọlọ́pa sèlérí àabò tó péye lásìkò ìbò

Òjísẹ́ Ọlọ́run pè fún Ìfaraẹnijì
March 6, 2019
Oyo ADC Stalwarts Debunk Defection Rumour
March 6, 2019
Iléesẹ́ Ọlọ́pa sèlérí àabò tó péye lásìkò ìbò

Níwọ̀n ba ọjọ́ diẹ tó kù tétò ìdìbò sípò Gómìnà àti ilé asòfin yóò wáyé lórílẹ̀èdè yíì, adelé ọ̀gágba ilésẹ́ ọlọ́pa ilẹ̀ yíì, Mohammed Adamu tisọ pé, àwọn òsìsẹ́ agbófinro ti gbaradì daadaa.

Ó sọ eléyi di mímọ̀ fáwọn oníròyìn lẹ́yìn ìpàdé àtilẹ̀kùn mọ́rí se àwọn òsìsẹ́ agbofinro àpapọ̀ pẹ̀lú Aàrẹ Muhammadu Buhari nílé ìjọba nílu Abuja.

Ọgbéni Adamu rọ àwọn ọmọ orílẹ̀èdè Nàijírìa láti tú yáyá jáde lọ dìbò lọ́jọ́ Sátidé láisi ìbẹ̀rù kankan.

Ọgágba àwọn ọlọ́pa sọ pé, wọ́n tún ti gbé ìgbésẹ̀ ètò àabò tó kọjá.

Gẹ́gẹ́ bóse wí, ilésẹ́ ọlọ́pa ti pinu láti fìyà tó dógbin jẹ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ da ètò ìdìbò náà ru.

Kemi Ogunkọla/Seyifunmi Ọlarinde

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *