Òjísẹ́ Ọlọ́run pè fún Ìfaraẹnijì

Àarẹ Buhari pè fún lílọ́wọ́ àwọn Ọba alayé nínú òsèlú
March 6, 2019
Iléesẹ́ Ọlọ́pa sèlérí àabò tó péye lásìkò ìbò
March 6, 2019
Òjísẹ́ Ọlọ́run pè fún Ìfaraẹnijì

Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lórílẹ̀èdè Nàijírìa se darapọ̀ mọ́ àwọn akẹgbẹ́ wọn yoku lágbaye láti sàmì ọjọ́ éérú tó bẹ̀rẹ̀ àawẹ̀, wọ́n ti wá ránwọn létí láti yàgò fún gbogbo àwọn ìwà àisedédé.

Òjísẹ́ Ọlọ́run Venerable Ọladipọ Ajọmọle tìjọ Anglican Ìbàdàn ló sàlàyé yíì nígbà tóníròyìn ilésẹ́ wa Radio Nigeria ńfọ̀rọ̀ wa lẹ́nuwò lórí ìbẹ̀rẹ̀ àawẹ̀ Lẹnti.

Venerable Ajọmọle gba àwọn Kristiani nímọ̀ràn láti lo àkókò náà láti máà yẹ ọkàn wọn wò kíwọ́n sì ma gbàdúrà láisimi àti lai saarẹ.

Nígbà tó ńsọ̀rọ̀ késí àwọn Kristiani láti gbàdúrà fún orílẹ̀èdè yíì lásìkò àawẹ̀ wá rọ wọn láti máà rántí àwọn èèyàn tókù diẹ káàto fún láwùjọ.

Kemi Ogunkọla/Seyi Olarinde

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *