Ẹgbẹ àwọn ọmọbíbí Ìlú Ìbàdàn sèlérí àtìlẹyìn fún Gọ́mìnà tílu díbò yàn

Ẹgbẹ́ àwọn Musulumi oníròyìn nípinlẹ̀ Ọyọ dùnú pẹ̀lú Seyi Makinde
March 13, 2019
Ilé Alájà Mẹ́ta wó pa àwọn Ènìyàn Nípinlẹ̀ Èkó
March 13, 2019
Ẹgbẹ àwọn ọmọbíbí Ìlú Ìbàdàn sèlérí àtìlẹyìn fún Gọ́mìnà tílu díbò yàn

Ẹgbẹ àwọn ọmọbíbí ìlú Ìbàdàn, CCII, ti sèlérí àtìlẹyìn wọn fún Gómìnà tílu dìbò yàn, ọ̀gbẹ́ni Seyi Makinde láti gbé Ìpínlẹ̀ Ọyọ débuté ògo.

Àrẹ àpapọ̀ ẹgbẹ́ náà, olóyè Yẹmi Soladoye ló sàlàyé yíì nígbà tó kó ikọ̀ ẹgbẹ́ sòòdí lọ kí Gómìnà tuntun náà.

Olóyè Soladoye tó sọ pé ẹgbẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn ti seti láti gbé ìmọ̀ràn àti èróngbà kalẹ̀ fún, ọ̀gbẹ́ni Makinde nígbà kúgba tó ba yẹ nígbàgbọ́ pé, àsìkò ìsèjọba rẹ̀ yóò so èso rere fáwọn aráalu.

Nígbà tó n fèsì, Gómìnà tílu dìbò yàn, ọ̀gbẹ́ni Seyi Makinde kan sáárá sègbè ọmọ Ìbàdàn lórí àbẹ̀wò wọn tósì fi ìgbáradì rẹ̀ han láti mú gbogbo ìlérí tóse sẹ.

Lẹ́yìn ọ̀ rẹyìn ni ikọ̀ yíì lọ se àbẹ̀wò ìbánikẹ́dùn sẹ́bí ọmọ ilé asojúsòfin táwọn kan pa Temitọpẹ Ọlatoye Sugar níbi tíya olóogbe náà ti bèèrè fúnsẹ́ ìwádi tí yóò tu àsírí àwọn tó pa ọmọ rẹ̀.

Iyaniwura/

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *