Fífi Ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí ọmọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìjọba se pàtàkì – Gómíná Akeredolu

Ìjọba àpapọ̀ ilẹ̀yí tise ìfilọ́lẹ̀ ìgbìmọ̀ amúsẹ́yá
March 27, 2019
Elected Members of Osun Assembly Get Certificate of Return
March 27, 2019
Fífi Ìwé ẹ̀rí ọjọ́ ìbí ọmọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìjọba se pàtàkì – Gómíná Akeredolu

Ìwé ẹ̀rí fífi ọjọ́ ìbí ọmọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìjọba ló ti pa dandan fún gbogbo ọmọ tó bá fẹ́ lọ fún ìtọ́jú níléwòsàn nípínlẹ̀ Òndó.

Gómìnà Oluwarotimi Akeredolu ló jẹ́ kéyi di mímọ̀ níbi ìpàdé àwọn tọ́rọkan lórí níní àkọọlé ọjọ́ ìbí nílu Àkúré, tósì sọ pé ìwé ẹ̀rí náà ni wan yo ma wò tọ́mọ bá fẹ́ bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ alákọ bẹ̀rẹ̀ yíká ìpínlẹ̀ Òndó.

Gómìnà Akeredolu tọ́kasi pé, yo sòro láti se tọ́jú àwọn ọmọ tí kò ni àkọọlé, ìdínìyí tó fi yẹ kí gbogbo òbí lọ fi orúkọ àwọn ọmọ sílẹ̀ fún ìlọsíwájú tó múnadoko.

Sáájú, nínú ọ̀ró rẹ̀, Ayaa Gómìnà arábìnrin Betty Akeredolu fi àidùnú rẹ̀ hàn pe kò dín ní ìlàjì àwọn ọmọ tọ́jọ́ orí wọn wà lábẹ́ márun nípinlẹ̀ náà, tí kò ní àkọọlé ọjọ́ ìbí.

Arábìnrin Akeredolu pẹ̀lú asojú àjọ tón rísí ètò ìkànìyàn, NPC, ọ̀gbẹ́ni Falusi Tunbọsun àti alákoso fún ètò ìlera, Dókítà Wahab Adegbenro sọpé ó lé ní milliọnu kan àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ tí kò ní akọọle ọjọ́ ìbí nípinlẹ̀ náà.

Wọ́n wá rọ gbogbo àwọn tó wà ní agbègbè ìgbèríko tófimọ́ asíwájú nínú ẹ̀sìn gbogbo àti àjọ tón rísí ètò ìkànìyàn láti fikún àyan wọn, lórí ètò ìpolongo kí gbogbo èyàn le mọ ànfàní tó rọ̀mọ́ gbígba ìwé ẹ̀rí fífi ọjọ ìbí ọmọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìjọba.

Ogunkọla/Odofin

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *