Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn, jẹ́jẹ ìpèsè ètò ìlera tó péjú owó

Akeredolu ńfẹ́ kí ilésẹ́ FRCN, tẹ̀síwájú nídi mímú àgbéga bá isẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́
April 9, 2019
Ọwọ́ pálába ọmọkùnrin kan ségi ńigba tó ńgbo owó lẹ́nu ẹ̀rọ lái lo káàdi
April 9, 2019
Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn, jẹ́jẹ ìpèsè ètò ìlera tó péjú owó

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn sàtẹnúmọ́, títẹramọ́ àfojúsùn rẹ̀ sétò ìlera tó péjuówó fáwọn èèyàn rẹ̀.

Alákoso fétò ìlera nípinlẹ̀ Ògùn, Dókítà Babatunde Ipaye, ẹnitó sọ̀rọ̀ ìdánilójú yíì lákokò tó ńbá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ nílu Abẹokuta, láti sàmì ayéyé àyájọ́ ọjọ́ ìlera fọ́dún 2019 sọpé ìpèsè òògùn àti ìtọ́jú tí o gara yóò wà kákiri láwọn ilé ìwòsàn jákè-jádò ìpínlẹ̀ náà.

Dókítà Ipayẹ sàlàyé pé pàtàkì àyájọ́ náà ní láti fanrere níní ànfàní gbogbo èèyàn sétò ìlera tópéjú owó.

Alákoso fétò ílera náà wá sàlàyé pé, ìpínlẹ̀ Ògún ti sàseyọ́rí lẹ́ka ètò ìlera rẹ̀ nípasẹ̀ fífún àwọn tóotóo ìdá mẹ́rìnlélọ́gọ́rin lábẹ́rẹ́ àjẹsára èyí tótayọ àfojúsùn ètò ìlera gbogbo-gbò tójẹ́ ìdá ọgọ́rin.

Segun Folarin/Elizabeth Idogbe

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *