Ọwọ́ pálába ọmọkùnrin kan ségi ńigba tó ńgbo owó lẹ́nu ẹ̀rọ lái lo káàdi

Ìjọba ìpínlẹ̀ Ògùn, jẹ́jẹ ìpèsè ètò ìlera tó péjú owó
April 9, 2019
FCE Students Stage Protest over Alleged Extortion By Management
April 9, 2019
Ọwọ́ pálába ọmọkùnrin kan ségi ńigba tó ńgbo owó lẹ́nu ẹ̀rọ lái lo káàdi

Ọjọ́ gbogbo ni tolè ọjọ́ kan ni tolóhun, báyíì ni ọ̀rọ̀ rí ní òwúrọ̀ òní ní ẹnu ẹ̀rọ tó ńpọ owó, tó wà nílé ìfowópámọ́ kan tó wà lẹ́gbẹ iléésẹ́ Radio Nigeria Dùgbẹ̀, Ìbàdàn nígbà ti ọmọkùnrin kan ń gba owó lẹ́nu ẹ̀rọ lái lo káàdi ìgba-owó.

ọmọkùnrin náà, Azeez Mọrufu tó ńgbé ní Ayẹ́yẹ́ ìbàdàn sọ pé òun ti máà ń se èyí tipẹ́ kí ó tó di pé ọwọ́ pálábá òun ségi.

Ọgbẹni Mọrufu ní tí òun bá ti tẹ àwọn nọ́mbà kan sí orí ẹ̀rọ náà, kía ni yóò sì máà pọ owó jáde.

Mọrufu ní àsírí rẹ̀ tú jáde lẹ́yìn tí ẹnìkan tó ń kọjá ri pẹ̀lú òbítíbitì owó tó ń gbà lẹ́nu ẹ̀rọ tó ńpọwó, tí ìmúra rẹ̀ tí ó dọ̀tí sì mú ẹni náà fura sí.

ẹnitíwọ́nfurasí náà ni wọ́n ti fà lé iléésẹ́ ọlọ́pa lọ́wọ́ fún ìwádi tó péjú owó.

Abisola Oluremi/Elizabeth Idogbe

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *