Ajàfẹ́tọ ọmọdé fọnrere ìjà tó gbópọn fún ìlòkulò ọmọdé

Ọmọ ológun gùnlé ìdánilẹ́kọ lórí àmúlò irinsẹ́ ìjagun
June 18, 2019
FCAAN Holds Training for Nigerian League Coaches in Ibadan
June 18, 2019
Ajàfẹ́tọ ọmọdé fọnrere ìjà tó gbópọn fún ìlòkulò ọmọdé

Bí ìwà lílo àwọn ọmọdé nílòkulò yóò ba dohun ìgbàgbé nílẹ̀ Nàijírìa, ìjọba gbọdọ̀ sèdásílẹ̀ àti àgbéjàde orúkọ àwọn èèyàn tó ba ń fọwọ́ pa idà òfin tóníse pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé lójú.

Ajáfẹ́tọ ọmọdé kan, Arábìnrin Ibukunoluwa Ọtẹsile ló gbọrọ àmọ̀ràn yíì kalẹ̀ l;akokò tó ń kópa lórí ètò ilé-isẹ́ wa kan lédè gẹẹsi tápeni “Straith Talk”, ti Radio Nàijírìa Ìbàdàn.

Arábìnrin Otẹsile sàlàyé pé, irú orúkọ àwọn èèyàn tíwọ́n bá sẹ́ẹ̀ sófin , tóníse pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àwọn ọmọdé náà, gbọdọ máà wà lárọwọ́tó àwùjọ gẹ́gẹ́ bíwọ́n se máà-ń se fáwọn agbésùnmọ̀mí láwọn orílẹ̀dè tó to gòkè àgbà lágbayé, kò sài fikun pé, irúfẹ́ ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ káwọn èeyàn máà sọ́ra se láwùjọ.

Bẹ́ẹ̀ ló sì tún beere fágbekalẹ̀ òfin tó lóórin, èyí tí yóò fààyè gba síse ìyádi fínífíní lákokò ìgbẹ́jọ́ àwọn èèyàn tó bá sẹ̀ sófin ìbálòpọ̀ kó lè ba jẹ kóríyá fáwọn èèyàn tó bá lúgbàdì ìsẹ̀lẹ̀ ìfipábánilópọ̀.

Kì sài bèerè fún ìdí tó fise pàtàkì kíwọ́n túbọ̀ gbọnwọ sowo tíwọ́n ńna sẹ́ka ètò, àti sàmúlò àwọn òfin tóníse pẹ̀lú rẹ̀, níbamu pẹ̀lú fífàyègbà gbogbo àwọn ọmọ ilẹ̀ adúláwọ̀ láti lè máà fífàyègbà pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ wọn láwọn orílẹ̀dè nín-ín.

Ajàfẹ́tọ ọmọdé náà wá gbórínyìn fún ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ, lórí bó se mú àgbéga bá owó tíwọ́n yàsọ́tọ̀ fẹ́ka ètò ẹ̀kọ́ nínú àbá ètò ìsúná nípinlẹ̀ yíì, àti bó se pàsẹ pé káwọn akẹ́kọ́ọ̀ má se san ẹgbẹ̀rún mẹ́ta Naira owó ilé-ìwé mọ́ gẹ́gẹ́ bí èyí tó jẹ́ àtẹ́wọ́gbà.

Kemi Ogunkọla/Mosope Kẹhinde

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *