Ọmọ ológun gùnlé ìdánilẹ́kọ lórí àmúlò irinsẹ́ ìjagun

Oyo INEC Undertakes Review of 2019 Polls
June 18, 2019
Ajàfẹ́tọ ọmọdé fọnrere ìjà tó gbópọn fún ìlòkulò ọmọdé
June 18, 2019
Ọmọ ológun gùnlé ìdánilẹ́kọ lórí àmúlò irinsẹ́ ìjagun

Ilé-isẹ́ ọmọ ológun ilẹ̀ yíì ti gùnlé ìgbésẹ̀ síse ìdánilẹ́kọ fáwọn òsìsẹ́ àbsdé lórí bíwọ́n se lè máà sàmúlò àwọn ǹkan ìjagun yíká orílẹ̀dè yíì.

Nígbà tó ńsọ̀rọ̀ níbi ìfilọ́lẹ̀ ètò ìdánilẹ́kọ náà olùdarí àgbà fẹ́kùn ilé-isẹ́ ọmọ ológun, ọ̀wọ́ kínni, tó wà nílu Kaduna, ọ̀gágun àgbà Faruq Yahaya sàpèjúwe ìdánilẹ́kọ ọ̀hún gẹ́gẹ́ bí èyí tó bọ sákìkò, níbamu pẹ̀lú ìpèníjà táwọn òsìsẹ́ asọ́bọdè ńkojú lẹ́nulọ́lọ́ọ̀yi, pẹ̀lú àwón onífàyàwọ́ láwọn enubodè tó ń bẹ nílẹ̀ yíì.

Ó wá gbóríyìn fákitiyan àwọn ọ̀gá àgbà asọ́bodè fún èróngbà wọn, tó sì wá rọ àwọn olùkópa láti sàmúlò ànfàní tíwọ́n  rí náà dáàda.

Nínú ọ̀rọ̀ tiẹ, olùdarí ètò ìdánilẹ́kọ náà, ọ̀gágun Emmanuel Agada sàlàyé pé, wọ́n sàgbékalẹ̀ ìdánilẹ̀kọ láti káwọn olùkópa mọ̀ nípa ọ̀kanòjọ̀kan àwọn ńnkan ìjagun, tíwọ́n ń sámúlò bí ìbọn ìléwọ́ àti Ak-47.

Àwọn òsìsẹ́ asọ́bodè bíì ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ lón kópa níbi ètò ìdánilẹ́kọ ọ̀hún.

Kemi Ogunkọla/Mosope Kehinde

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *