Ìjọba ìpínlè Èkìtì sèkilọ̀ lori fifì tipátipá gba ilẹ̀

Ekiti to Accelerate Infrastructure Development, Check Quackery
July 11, 2019
Oyo Assembly Asks Agencies to Rid State of Destitute, Beggars
July 11, 2019
Ìjọba ìpínlè Èkìtì sèkilọ̀ lori fifì tipátipá gba ilẹ̀

Ìjọba ìpínlè Èkìtì tí sọ pé ẹnikẹ́ni towo bá tè tòun fi tipátipá gba ilẹ̀ tàbi tó ngba nkan ìní lọ́nà tí kò bófin mú, ni yo ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin gbara tàbí kó san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà edegbeta náírà.

Igbakeji Gómìnà, Otunba Bisi Egbeyemi ló sísọ lójú ọ̀rọ̀ yi láàfin Ewì tilu Ado Èkìtì lásìkò ìpolongo lórí òfin todùn 2019, èyí tí Gómìnà Kayode Fayemi ṣẹ̀ṣẹ̀ buwolu, lórí ìlànà tí wọ́n ti là kalè láti dabobo ẹtọ àwọn onile.

Otunba Egbeyemi so pé, ìgbéṣe náà yo pinwo àwọn tó ń fi tipátipá gba ilẹ̀, tó sì tun lo àkókò náà láti ṣe ìdánileko fún àwọn olóyè tó fi mọ àwọn olórí ẹbí.

Bakana, Ogagba leka tí wọn tin gbé òfin ró ńipinle Èkìtì, Ogbeni Akininyeme Akpan sọ síwájú pé ẹnikẹ́ni tó bá gbé ìgbéṣe àìtó nípa Lilo ohun ìjà tàbí ogún ìbílè láti lé ẹ̀yan kúrò lórí ilẹ̀ wọn ní wón yo lọ sí ẹ̀wọ̀n tàbí kí wọ́n sanwó ìtanràn.

Nígbà tó ń fèsì, Ewì tilu Ado Èkìtì, ọba Adeyemo Adejugbe gbóríyìn fún ìjọba ìpínlè Èkìtì fún àwọn ìgbéṣe tó gbé láti fòpin sí bí wọn ṣe ń fi tipátipá gba ilẹ̀ ńipinle náà.

Kemi Ogunkola/Ladele

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *