Ilé ìgbìmò asofin ìpínlè Ọ̀yọ́ fofin gbe ituka àjọ eleto ìdibo

Ogagba tuntun fun NNPC jeje láti ṣe atunto àjọ òhun
July 11, 2019
FERMA to Repair Damaged Roads in Ekiti
July 11, 2019
Ilé ìgbìmò asofin ìpínlè Ọ̀yọ́ fofin gbe ituka àjọ eleto ìdibo

Ilé ìgbìmò asofin ìpínlè Ọ̀yọ́ ti fofin gbe ituka àjọ eleto ìdibo ẹ̀ka tipínlè Ọ̀yọ́ lẹ́yìn, níbamu pẹ̀lú ìkéde igbese náà tí Gómìnà Seyi Makinde ṣe.

Èyí tẹle ọ̀rọ̀ tonise pẹ̀lú pàtàkì ìfẹ́

awọn aráàlú lórí atungbeyewo ìṣe àjọ eleto ìdibo ńipinle Ọ̀yọ́, lórí ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ àti ìjọba ìbílè alabode, èyítí olórí ọmọ ẹgbẹ́ tó pọ̀ju nílé ìgbìmò asofin ńipinle Ọ̀yọ́, Ogbeni Sanjo Adedoyin tó ń soju ẹkùn ìdìbò Ogbomoso gbékalè.

Ogbeni Adedoyin bèrè pé kí leè kéde ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ ọjọ́ kejidinlogun oṣù karùn-ún ọdún 2018 tó gbé àwọn alága ìjọba ìbílè alabode sípò gẹ́gẹ́ bí èyítí kò bófin mú, ká gbékalè ìgbìmò min sì wá tí yóò ṣètò ìdìbò tí ó lèjá ń bákan nínú.

Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àgbékalè ọ̀rọ̀ náà, ọmọ ẹgbẹ́ tó ń soju ẹkùn ìdìbò Itesiwaju, Ogbeni Dele Adeola, láti inú ẹgbẹ́ òsèlú P. D. P, bẹnu atelu ètò ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ alabode náà pẹ̀lú àlàyé pé, ìjọba ìbílẹ̀ ónidagbasoke kò sí lábẹ́ níbamu pẹ̀lú abala kokanlenigba òfin ọdún 1999.

 

Kemi Ogunkola/Adebisi

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *