Àarẹ Muhammadu Buhari ti kí olóotu ìjọba tuntun nílẹ̀ Gẹẹsi

Ilésẹ́ ọlọ́pa ìpínlẹ̀ Ògùn gbé ìgbésẹ̀ akin
July 25, 2019
X-ray of President Buhari’s Ministerial List before Senate
July 25, 2019
Àarẹ Muhammadu Buhari ti kí olóotu ìjọba tuntun nílẹ̀ Gẹẹsi

Àarẹ orílẹ̀dè yíì, Muhammadu Buhari ti kí olóotu ìjọba tuntun nílẹ̀ gẹẹsi, ọ̀gbẹ́ni Boris Johnson, kú oríre.

Nínú isẹ́ ẹkú oríire tó rán èyí tólùrànlọ́wọ́ pàtàkì rẹ̀ fétò ìròyìn àti ìbáralusọ̀rọ̀ Mallam Garba Sheu fọwọ́sí, làarẹ ti sàlàyé pé ilẹ̀ Nàijírìa bu ọlá fún ìpinu tilẹ̀ gẹẹsi se ń tó sì setán láti sísẹ papọ̀ pẹ̀lú olóotu ìjọba tuntun ọ̀hún, pẹ̀lú àlàyé pé, ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀dè tó se gbọ́kànlé nilẹ̀ gẹẹsi jẹ́, papa jùlọ lẹ́ka àgbéga ọ̀rọ̀ àbò àti gbígbógun ti ìwà ìbàjẹ́.

Àarẹ Buhari tọ́kasi pé, ilẹ̀ Nàijírìa yóò túbọ̀ tẹpẹlẹmọ́ àjọsepọ̀ tó wà láàrin rẹ̀ àtilẹ̀ géési pẹ̀lú olóotu ìjọba tuntun náà.

Akọ̀wé àgbà tẹ́lẹ̀ fọ́rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, nílẹ̀ gẹẹsi, ọ̀gbẹ́ni Boris Johnson niwọ́n yàn lábẹ́ Asia ẹgbẹ́ òsèlú Conservative láti gbapò lọ́wọ́ aríbìnrin Theresa May.

Wojuade

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *