Àjọ PCRC sèrànlọ́wọ́ lati ti ilé-isẹ́ ọlọ́pa lẹ́yìn.

Agriculture will enhance revenue generation – OYCCIMA
July 31, 2019
Ìjọba àpapọ̀ gbé ìgbìmọ̀ tuntun kalẹ̀ fún àjọ AMCON
July 31, 2019
Àjọ PCRC sèrànlọ́wọ́ lati ti ilé-isẹ́ ọlọ́pa lẹ́yìn.

Adarí ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ, ọ̀gbẹ́ni Debọ Ogundoyin sọpé akitiyan ìgbìmọ̀ tón sisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ilé-isẹ́ ọlọ́pa àtagbègbè, PCRC, nílẹ̀ yíì, ti sèrànlọ́wọ́ aláilẹ́gbẹ́ nídi titi akitiyan ilé-isẹ́ ọlọ́pa lẹ́yìn, lọ́nà àti dábòbò ẹ̀mí àti dúkia aráalu.

Adarí ilé náà fìdí èyí múlẹ̀ lákokò táwọn asojú ìgbìmọ̀, PCRC, nípinlẹ̀ Ọyọ wá sàbẹ̀wò si lọ́fìsì rẹ̀, èyí tálaga ìgbìmọ̀ ọ̀hún, ẹniọ̀wọ̀ Peter Ọmọfoye kósòdí.

Kò sài tẹnumọ́ pé, gbogbo ọ̀nà nìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ ńsán láti mágbega bọ́rọ̀ àláfìa àtààbò nípinlẹ̀ yíì pẹ̀lú àfikún pé, láisi ètò àbò kòlé sí ìdàgbàsókè kan dàbí alárà ní gbogbo ẹ̀ka ètò ọrọ̀ ajé tón bẹ nílẹ̀ yíì.

Ọgbẹni Ogundoyin wá tẹnumọ́ ìdí tófi sepàtàkì fún ìjọba nígbogbo ẹ̀ka láti sàtìlẹ́yìn fún èròngbà ìgbìmọ̀, PCRC, papa jùlọ nídi akitiyan wọn látiridájú pé àjọsepọ̀ tó dánmọ́rán wà láarin ilé-isẹ́ ọlọ́pa àtaarálu.

Sáájú nínú ọ̀rọ̀ tìẹ, alága ẹgbẹ́, PCRC, nípinlẹ̀ Ọyọ, ẹniọ̀wọ̀ Peter Ọmọfoye tó sàlàyé pé, ìgbìmọ̀ náà kó lé sàseyọrí kan gbogì tí kò bá sí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìjọba àtàwọn ọmọ ilẹ̀ yíì.

Ó wá bèèrè fún àjọsepọ̀ tó dánmọ́rán láarin ìgbìmọ̀ náà àtilé asòfin ìpínlẹ̀ Ọyọ.

Wojuade

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *