Ìjọba àpapọ̀ gbé ìgbìmọ̀ tuntun kalẹ̀ fún àjọ AMCON

Àjọ PCRC sèrànlọ́wọ́ lati ti ilé-isẹ́ ọlọ́pa lẹ́yìn.
July 31, 2019
Role of Journalists remains invaluable – Ondo info commissioner
July 31, 2019
Ìjọba àpapọ̀ gbé ìgbìmọ̀ tuntun kalẹ̀ fún àjọ AMCON

Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀èdè yíì ti gbé ìgbìmọ̀ tuntun kan kalẹ̀ látiridájú pé, wọ́n rí owó tó lé ní Trilliọnu márun náirà gbèsè tó jẹ́ tàjọ tó n mójútó dúkia ìjọba nílẹ̀ yíì, AMCON,  gbà padà.

Igbákejì Àaré ilẹ̀ yíì, ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmi Iṣinbajo ló fìdí èyí múlẹ̀ lákokò ìpàdé kan tó sepẹ̀láwọn ọmọ ìgbìmọ̀ àtàwọn alábojútó AMCON, tófimọ́ àwọn adarí kọ̀ọ̀kan láwọn àjọ tíjọba tó wáyé nílé Àarẹ tó wà nílu Abuja.

Lára àwọn àjọ náà latarí, àjọ tó ńgbógunti sísowólu kúmọkùmọ, EFCC, àti akẹgbẹ́ rẹ̀ ICPC, ẹ̀ka ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ lórí ọ̀rọ̀ ìsúná nílẹ̀ yíì, tófimọ́ àwọn akọ̀wé àgbà lẹ́ka ètò ìjájọ́ àti tàwọn ilé-isẹ́ tóńrísétò ìrìnà.

Ọjọgbọn Ọṣinbajo wá sọ́ọ́di mímọ̀ pe, gbogbo àwọn àjọ rọ́rs kan gbọdọ̀ fikún akitiyan láti lè sàseyọrí nídi èròngbà wọn, pẹ̀lú àfikún pé, ìgbìms tíwọ́n sàgbékalẹ̀ ọ̀hún gbọdọ̀ bojuwo àwọn onígbèsè bí ogún tó se kókó lájọ AMCON, kíwọ́n sì tètè gbé ìgbésẹ̀ tó bá yẹ lórí rẹ̀.

Sáájú ni igbákejì Àarẹ náà ti kọ́kọ́ báwọn alábojútó àjọ AMCON, sèpàdé lọ́jọ́ karun èyí tíwọ́n fi dìjọ jíròrò lórí ọ̀nà tíwọ́n yóò fi yanjú gbèsè náà.

Wojuade

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *