Makinde fọwọ́sí ọgọ́ta míllíọ́nu náirà fàwọn akẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin

Ẹgbẹ́ òsìsẹ́ ìpínlẹ̀ Ọyọ sọ ísepàtàkì owó osù tuntun
August 7, 2019
Ekiti Students Protest Alleged Unlawful Arrest of Colleagues
August 7, 2019
Makinde fọwọ́sí ọgọ́ta míllíọ́nu náirà fàwọn akẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ, onímọ̀ ẹ̀rọ Seyi Makinde ti fọwọ́sí ọgọ́ta míllíọ́nu náirà fọ́gọ́fà àwọn ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọyọ, tíwọ́n ńkẹ̀kọ́ọ lọ́wọ́ nílé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin nílẹ̀ Nàijírìa.

Àná òde yíì ni Gómìnà Makinde gbàlejò ikọ̀ àwọn akẹ́kọọ tón kẹ́kọọ nípa ìmọ̀ òfin lọ́fìsì rẹ̀, tó sì gbàwọ́n níyànjú láti ní ìfaradà lẹ́nu ètò ẹ̀kọ́ wọn.

Àtẹ̀jáde kan táwọn àgbà fétò ìròyìn sí Gómìnà, ọ̀gbẹ́ni Taiwo Adisa fọwọ́sí, ló ti fìdí fífowó owó náà múlẹ̀ láti fi tẹ̀síwájú lẹ́nu ètò ẹ̀kọ́ wọn.

Gómìnà Makinde wá rọ àwọn akẹ́kọ́ọ̀ náà látiridájú pé, wọ́n padàwálé láti wá kópa tó jọjú sídàgbàsókè ìpínlẹ̀ Ọyọ lẹ́yìn tíwọ́n bá parí ètò ẹ̀kọ́ wọn tán.

Nígbà tón fèsì, olórí àpérò àwọn akẹ́kọ́ọ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Ọlaniyi Ogunlade dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wa Gómìnà tó sì sèlérí pé, òun àtàwọn akin ẹgbẹ́ òun yokù yóò mu ǹkan rere jáde lẹ́nu ẹ̀kọ́ ìmọ̀ òfin wọn, tó yóò sì jẹ́ akẹ́kọ́ọ̀ iru ẹ̀ nínú ìtàn ìpínlẹ̀ Ọyọ.

A ó rántí pé, ọdún 2012 làwọn akkkọ́ọ̀ tón kọ́ nípa ìmọ̀ òfin tíwọ́n jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ọyọ, ti gbarúfẹ́ owó báyíì sẹ́yìn.

Wojuade

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *