Iléésẹ́ ìrìnà ojú omi pinnu rẹ̀ láti sisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Òndó

Aarẹ Buhari sìde ètò ìdánilẹ́kọ fáwọn alákoso tuntun
August 19, 2019
Stakeholder Identifies Challenges of Humanitarian Services
August 19, 2019
Iléésẹ́ ìrìnà ojú omi pinnu rẹ̀ láti sisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Òndó

Iléésẹ́ tó ńrísí àkóso ìrìnà ojú omi lórílẹ̀èdè yíì, NPA, ti sàfinhàn ìpinnu rẹ̀ láti sisẹ́ pọ̀ pẹ̀lú ìpínlẹ̀ Òndó lórí àkànse isk ibùdókọ̀ ojú omi rẹ̀ tó ńlówó, láti fi mú àgbéga bá ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà.

Ọga àgbà iléésẹ́ náà, lẹ́ka tó ńbújútó àgbékalẹ̀ ìlànà gbogbo àti ọ̀rọ̀ ìròyìn àjọ ná, ọ̀gbẹ́ni Adams Jato, tó sísọ lójú ọ̀rọ̀ yíì níbi ìpàdé oníròyìn kan, sàlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn ibùdókọ̀ ojú omi ni kò ti ma sisẹ́ tó bó se yẹ fún àwọn ìdí kan tájọ náà ti ńsisẹ́ lé lórí báyi.

Ọgbẹni Jado sàlàyé síwájú si wípé, ìjọba ìpínlẹ̀ Òndó ti sọ̀rọ̀ náà ní ẹni tó nígbà láà fọ̀rọ̀ lọ̀, nípa bóse kọ ìwé kan sí àjọ tó ńsàkoso ìgbòkègbodò ìrìnnà ojú omi, léyi tájọ ọ̀hún sì ti setán láti sàtìlẹyìn fún, kí ibùdókọ̀ ojú omi olokola, báà lè di orísun ajé, sípèsè isẹ́ àti ìdókowò tó gbọngbọ́n láti mú kí ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Òndó gbérù si.

Babatunde Tiamiyu

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *